E dake isokuso Biyi Otegbeye atawon oludije ADC yoooku si duro digbi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 20 September 2022

E dake isokuso Biyi Otegbeye atawon oludije ADC yoooku si duro digbi




Won ti kilo fawon onisokuso ti wọn gbe aheso kaakiri pe Agbejoro Biyi Otegbeye, oludije gomina fegbe oselu ADC nipinle Ogun atawon ondije yooku pe won ko kopa mo nitori oruko won ko jade.

Won ni iro to jinna si ooto ni nitori pe titi di akoko ta a n ko iroyin yii lowo, ese oludije naa ko ye rara ati pe o di ojo kerin osu to n bo yii ti ajo eleto ibo ba gbe asekagba oruko awon oludije jade ni won yoo ri okodoro oro.

Gege bi atejade tawon iko iroyin oludije Biyi Otegbeye gbe jade lale yii lati fi tako awon aheso oro naa.

Won so pe atejade tawon eeyan ohun gbe kaakiri ni eyi to koko jade ninu iwe iroyin oloyinbo Vanguard, lojo ketalelogun, osu keje, odun yii nigba ti ajo INEC koko gbe e jade ko to di pe atunse waye.

Won was so leekan si pe ojo kerin, osu kewaa, iyen osu to n bo yii ni ojulowo oruko yoo ti jade.

Gege bi won se wi, won nitori pe egbe oselu APC ati PDP ti su awon araalu ti won si ti n wa ona abayo si ADC lọ je ki won maa gbe igbekugbe bee kaakiri.

Won so pelu idaniloju pe ki I se pe Biyi Otegbeye jade dupo nikan bi ko se pe yoo wole fun ipo gomina lodun 2023, lagbara Olorun.

Bee ni won ro awon araalu lati ma se je kawon obayeje yii si won lokan.

No comments:

Post a Comment

Pages