O tipẹ tawọn eeyan ti n sọ, o tipẹ ti wọn si ti n woye pe ṣe bi ipinlẹ Ogun, yoo ṣe tun maa ba a lọ ree, ninu gbogbo idojukọ ti wọn n fojoojumọ koju, ṣe bawọn yoo ṣe ku sinu ìṣẹ́ oun iya, ati ipọnju ojoojumọ tawọn to ṣejọba lati bi ọdun mẹrin n ko awọn si.
Bi a ba si ni ka sọ tootọ, inu oyun gan-an mọ pe nnkan ko rọrun fawọn araalu, ṣe ni gbogbo ẹ n le koko si, tina ijọba to daku daji ni ka sọ ni, abi omi ti ko si, to jẹ pe tipatipa lawọn kan fi n ri omi mu, ẹ jẹ ka dupẹ lọwọ awọn kan ti wọn fi kanga dẹrọ ṣe awọn araalu loore, ti wọn ko si nijoba .
Oju ọna n kọ, ọpọ awọn to n gbe ibi ti wọn ti ni idojukọ ọna, ni wọn ti sa kuro nibi ti wọn n gbe, nitori ti wọn ko ri ẹni to le ran wọn lọwọ, to si jẹ pe agunla nijọba to wa lode yii fi wọn da, ti wọn ko ba tii pariwo wọn lori redio tabi tẹlifiṣan ati iwe iroyin, wọn ko mọ pe o yẹ kawọn ṣe atunṣe.
Bi wọn ba tun ṣe e tan, ko ni pẹ, ko nijinna tawọn ọna ọhun yoo tun fi bajẹ ju bo ṣe yẹ lọ, gbogbo awọn nnkan wọnyii lo mu ki awọn araalu sọ pe ọrọ oloṣelu ti si awọn, boya lawọn yoo kopa nibi ibo to n bọ.
Ṣugbọn ọpọ ti n yi ipinnu ẹ pada p, bẹẹ ni, wọn ti n yi pada, wọn ti sọ pe pẹlu oludije gomina tuntun to n bọ yii, awọn ṣetan lati fibo wọn wọn gbe e wọle, nitori ẹni tawọn mọ pe Ọlọrun fẹẹ lo latigba kuro ninu iṣẹ ati iya ni.
Wọn ko ti i si nijọba, awọn eeyan ti mọ ipa to ti ko ninu igbe aye ọpọ awọn eeyan, o si dawọn loju pe to ba depo gomina lọdun 2023, yoo tun ṣe ju bẹẹ lọ, nitori lati inu oyun ni Ọlọrn ti fi omi aanu si loju, o tun waa dele aye tan, o tun tẹsiwaju.
Njẹ ta a ni ẹni naa, hmmm, bi a ba pe ori akọni, afi ida laalẹ, Agbẹjọro Olubiyi Ọtẹgbẹyẹ, ti ọpọ mọ si BOT, ni ẹni naa, oun lawọn eeyan ipinlẹ Ogun fojoojumọ ṣatilẹyin fun un pe to ba ti ya a, o ti ya, bawọn Yewa ṣe sọ pe ọmọ wa ni bẹẹ lawọn Ijẹbu naa sọ pe ọmọ wa ni awọn Ẹgba tiẹ wa sọ pe gbogbo ara lawọn fi gba, nitori akoko ti Ọlọrun fẹẹ lo fun gbogbo wọn lapapọ ni.
Biyi Ọtẹgbẹyẹ, ta a n sọ yii, Ta a ni?, Nigba to wa ni ogun ọdun, lo jade nileewe giga yunifasiti ti Eko, O di ọga ileeṣẹ Brokerage Firm, nigba to wa lọmọ ọdun mẹtalelogun, Nigba to si da ileeṣẹ adojutofo silẹ adojutofo tiẹ silẹ lọmọ ọdun mọkandinlọgbọn.
Lọdun 2013, ni wọn fi ṣe alaga igbimọ ileewe giga yunifasiti, Uyo, bẹẹ lo tun da ajọ ẹlẹyin aanu kan silẹ to pe ni Building Opportunities for Tomorrow iyẹn BOT. Oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, ta a n sọrọ ẹ yii tun kẹkọọ nipa imọ ofin, to si kawe gboye agbẹjọro agba iyẹn Barrister and Solicitors of the Supreme ni 2003.
Ọkunrin yii ki i ṣe pe o ṣẹṣẹ bẹrẹ oṣelu, ẹ jẹ ka sọ pe inu ẹjẹ ẹ lo wa ọmọ ẹgbẹ oṣelu Adc lo wa, ni wọọdu kin in ni, Ilaro, ko to darapọ mọ wọn lo ti wa ninu ẹgbẹ APC, ni 2015, oun ni SDP fa kalẹ fun ipo sẹnetọ, fun ẹkun Ogun West, nigba to di 2019, oun ni APC fa kalẹ gẹgẹ bi oludije fun ipo aṣoju ṣofin, fun ẹkunYewa South/ ipokia.
Pẹlu awọn nnkan ti a ti sọ silẹ atawọn mi-in ta o tun sọ lọjọ iwaju, o ti fihan gbangba pe oloṣelu to moye, to mọ nnkan tawọn awọn araalu n fẹ, to yatọ sawọn aṣawọ, ni Biyi ọmọ Ọtẹgbẹyẹ, asiko si ti to lati fawọn ọmọ ipinlẹ Ogun, lati fa ire wọlẹ nipa atilẹyin wọn ati Ọlọrun fun oludije naa labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, nitori oun ni ajanaku ti wọn n reti pe o le ṣe e.
No comments:
Post a Comment