Ọpọ awọn to gbọ nipa idajọ ẹjọ kotẹmilọrun to waye lọjọ Monde, ọsẹ yii, nibi ti wọn ti olupẹjọ Ṣẹgun Ṣowunmi, to n dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun, lare lati maa ba ẹjọ ẹ tile - ẹjọ giga kan niluu Abẹokuta, ti kọkọ danu lọ, ni ọrọ naa ko yee, ti wọn si n beere kin in o tumọ si ati bi ariwo ṣe n lọọ nigboro pe Ṣowunmi ṣi ni oludije ipo gomina.
Ninu iwe ipẹjọ naa ti nomba ẹ jẹ CA/IB/243/2022, ti Ṣẹgun Ṣowunmi, ti pe awọn ẹgbẹ oṣelu PDP, igbimọ apapọ ẹgbẹ ọhun ati Ladi Adebutu sile - ẹjọ ko tẹmilọrun ọhun tawọn adajọ mẹta kan, Chidi Nwaoma, Abba Mohammed ati Usman Musale ṣedajọ le lori.
Nigba to n gbe idajọ ọhun kalẹ, Adajọ Usman Musale, to ka idajọ ọhun lorukọ awọn mẹtẹẹta sọ pe Adajọ A Akinyẹmi, tile ẹjọ giga, to wa niluu Abẹokuta, to kọkọ da ẹjọ ọhun kuna lati da ẹjọ naa nu ati pe o lẹtọọ labẹ ofin lati gbọ ẹjọ ọhun.
Gẹgẹ bi awọn agbẹjọro ṣe wi pẹlu idajọ ti wọn gbe kalẹ ọhun, wọn ni Ṣẹgun Ṣowunmi atawọn yooku ti wọn jọ dije dupo oludje gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, ṣi wa nibẹ titi ti wọn yoo yun fi gbe idajọ mi-in dide .
Ninu ẹjọ ti Ọkunrin ọmọ bibi ilu Abẹokuta ọhun ti kọkọ pe nile-ẹjọ giga to wa niluu Abẹokuta, lo ti sọ pe awọn oloye ẹgbẹ naa fi sapakan ju ọkan lọ, nitori bi wọn ṣe gba fọọmu mo fẹẹ dije fun Adebutu, ti wọn ko gba fawọn oludije yooku ṣugbọn tile ẹjọ ọhun da ẹjọ naa nu to ni oun ko le gbọ nitori awọn abala ofin kan ti ọdun 1999.
Idi si niyii, Ṣowumi ṣe gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ niluu Abuja, lati bawọn foju agba wo , ṣugbon ti Adajọ to ka idajọ ọhun, fun wakati kan sọ pe o yẹ , o si lẹtọọ ki igbẹjọ naa maa lọ nile-ẹjọ giga to n gbọ tẹlẹ
No comments:
Post a Comment