Agba oloṣelu nni, Ọnarebu Moshood Salvador, ti sọ pe idi toun fi fẹgbẹ oṣelu APC silẹ lọọ darapọ mọ Labour, nibi to ti fẹẹ jade dupo fun gomina nipinlẹ Eko, ni bi ẹgbẹ to wa tẹlẹ ko ṣe ṣe daadaa sawọn ọmọlẹyin ẹ.
Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n kede pe oun ti darapọ mọ ẹgbẹ tuntun. O sọ pe awọn ko ri anfaani kankan lati ọdun 2018, tawọn kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP bọ si APC, o ni lẹyin ti wọn ti lo awọn tan, ni wọn sọ wọn di ohun elo alopati.
Oludije gomina fẹgbẹ oṣelu Labour, ninu ibo to n bọ lọdun 2023, tun sọ pe gbogbo ileri ti APC, ṣe fawọn atawọn ọmọlẹyin oun ni wọn ko mu ṣẹ raraba awọn oniroyin sọrọ nibi etto ṣẹṣẹ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Labour, ti ṣalaye idi to fi fẹgbẹ APC, tipinlẹ Eko, to wa silẹ.
Lara awọn ileri ọhun gẹgẹ bo ṣe ṣalaye ẹ ni fifun wọn ni ipo kọmiṣanna meji, gbigba ọgọrun-un ninu awọn ọmọ ẹyin ẹ ṣiṣẹ si LASTMA,, amọ to jẹ pe ori ahọn ni gbogbo rẹ ja si. O ni awọn ko si tun ni waa jẹ ki wọn fi ọgbọn ete de awọn mọlẹ mọ, idi niyii tawọn si fi ṣe tẹsiwaju ninu oṣelu
Salvador sọ pe oun atawọn eeyan oun tawọn jọ wa ni ‘Conscience Forum’, ti wa pinnu lati bọ sinu ẹgbẹ Labour. O ni latigba tawọn ti darapọ mọ wọn lawọn ti jọ n ṣiṣẹ pọ, ṣugbọn awọn ṣẹṣẹ kede ẹ raye pe omi tuntun ti ru o.
O ni iyi tawọn ri ninu ẹgbẹ oṣelu tawọn ṣẹṣẹ darapọ mọ yii lagbara debi pe wọn tun fawọn ọmọlẹyin oun lati lanfaani lati dije fun ipo to ba wu wọn. Bẹẹ lo sọ pe ni nnkan bi ọsẹ kan sẹyin loun atawọn eeyan oun jọ forikori, ti wọn si sọ pe ki oun wa dije fun ipo goimina labẹ ẹgbẹ oṣelu naa, ti mo si gba.
O ni ‘’ Lakooko naa ni mo rọ awọn ẹgbẹ oṣelu Labour, ki wọn juwọ ẹni to ti dije fun ipo gomina tẹlẹ silẹ fun mi, eyi ti wọn si ṣe. Emi nikan ni mo gba fọọmu lati dije fun ipo gomina, ti mo si ti da a pada sọdọ alaga ẹgbẹ naa lapapọ. Gbogbo wa si ti ṣeleri lati jọ ṣiṣẹ pọ, Ọlọrun yoo si ran wa lọwọ’
Lara awọn to wa nib lọjọ naa ni igbakeji alaga ẹgbẹ naa lapapọ, Lamido Apanpa,ati alaga ẹgbẹ naa nipnlẹ Eko, Ṣeyi Ṣowunmi.
No comments:
Post a Comment