Digbi ni mo ṣi wa ninu ẹgbẹ oṣelu APC-Biyi Ọtẹgbẹyẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 8 July 2022

Digbi ni mo ṣi wa ninu ẹgbẹ oṣelu APC-Biyi Ọtẹgbẹyẹ


Agbẹjọro Biyi Ọtẹgbẹyẹ ti sọ pe ko si ootọ ninu ọrọ tawọn kan n sọ pe oun ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC, bọ sinu PDP, o ni irọ patapata gba a ni.

Ọkunrin naa sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita, o sọ pe ahesọ ọrọ lawọn eeyan naa n gbe kaakiri ati pe titi di akoko yii digbi, loun ṣi wa ninu ẹgbẹ APC.

Ọtẹgbẹyẹ to dije dupo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu ọhun tun sọ pe oun ko mọ ibi tawọn ti wọn gbe iroyin naa ti ri nnkan ti wọn gbe. O ni tọkantọkan oun loun fi wa ninu ẹgbẹ yii.

Ati pe oun ṣiṣẹ pọ pẹlu ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, lati rii pe Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, to jẹ oludije fun ipo aarẹ ninu ibo to n bọ jawe olubori lọdun 2023.

O waa fi akoko naa rọ awọn alatilẹyin ẹ ti wọn jọ n wa ilọsiwaj ẹgbẹ APC lati duro ti ẹgbẹ naa titi ti wọn yoo fi jawe olubori ninu ibo aarẹ to n bọ. Pẹlu adura pe ki Ọlọrun ko fun wọn lẹmi aṣeyọri.


No comments:

Post a Comment

Pages