Ẹ má sinmi àdúrà lórí ètò ààbò àti ọ̀rọ̀ ajé orílèèdè yìí-Ṣàràki - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 8 July 2022

Ẹ má sinmi àdúrà lórí ètò ààbò àti ọ̀rọ̀ ajé orílèèdè yìí-ṢàràkiDokita. Abubakar Bukọla Ṣaraki, to jẹ olori ile igbimọ aṣofin tẹlẹ lorileede yii, ti rọ awọn ọmọ Naijiria, lati ma ṣe dakẹ adura lakooko ta a wa yii lori eto aabo ati ọrọ  aje .

 

Ọkunrin naa sọrọ ọhun ninu atẹjade ikini ku ọdun ileya to fi sita, eyi ti Alaaji Yusuph Olaniyonu, to jẹ akọwe iroyin ẹ fi sita lorukọ olori ile igbima aṣofin tẹlẹ naa.

 

O sọ fun wọn pataki ọdun ileya gẹgẹ bi eyi to duro fun ifira ẹni kalẹ ninu igbagbọ, ki wọn si ma ṣe gbagbe lati jẹ ki alaafia jọba nibi gbogbo ti wọn ba wa.

 

Bẹẹ lo tun rọ awọn musulumi ododo ti wọn wa Mẹka lati lo akoko naa fi gbadura fun iṣọkan, aabo, alaafia ati ẹmi gungun fun orileede yii nitori bi nnkan ṣe n lọ, ti ko rọgbọ.

 

 

O tun sọ pe “Akiyesi kan ti mo fẹẹ ki a ṣe ni pe akoko ọdun ileya yii n polongo, oṣi,ainiṣẹ ati ebi lorileede yii nitori ọpọ awọn eeyan wa ni wọn ko le sọdun yii nitori bi nnkan ṣe le koko mọ wọn, ti wahala to n waye ti sọ awọn kan di alainilegbe, tawọn kan si tun ti padannu ẹmi eeyan wọn, tawọn kan si tun wa ni igbekun awọn ajinigbe.

 

“Bi nnkan ṣe n lọ yii ti mu ki nnkan su awọn eeyan, ti inu wọn ko dun, ti wọn si ti yọ idunnu kuro ninu adun wọn, bo tilẹ jẹ pẹ ọpọ awọn eeyan ni wọn ko ba jade  sita lati lọ si yidi fun adura ọdun, lati fọpẹ fun Ọlọrun, mo wa rọ wọn lati lo akoko naa lati fi dupẹ lọwọ Ọlọrun Allah, amọ ti wọn ko le ṣe bẹẹ nitori bi nnkan ṣe ri bayii.

 

 

“Awọn musulumi orileede yii gbọdọ fimọ sọkan lati gbadura si Ọlọrun fun idariji, ko si da alaafia pada si orileede yii, ki o wo orileede wa san, ki o si ran wa lọwọ lati gba wa lọwọ awọn to doju ogun kọ wa.

 

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages