Ẹ jẹ ki awọn to n pa eeyan nipakupa rija alaalẹ- Ọlọfin Adimula - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 19 June 2022

Ẹ jẹ ki awọn to n pa eeyan nipakupa rija alaalẹ- Ọlọfin AdimulaAjọ to n ri si aṣa ati iṣẹṣe ti wọn pe ni Ọlọfin Adimula, ti rọ Ọlọwọ tiluu Ọwọ, Ọba Ajibade Ogunoye, lati gba awọn alaalẹ laaye lati kọju ija sawọn to n pa awọn eeyan nipakupa.

Ninu atẹjade ti Alaaji Raheem Sabina to jẹ aarẹ ẹgbẹ naa ati Kọmureedi Akinpẹlu Adeṣina, fi sita lati fi ẹhonu wọn han lori awọn tawọn kan lọọ ka mọ ṣọọṣi St. Francis Catholic Church,nibi ti wọn ti da ẹmi ọpọ eeyan legbodo.

 

Wọn ni wọn ko gbọdọ jẹ kawọn eeyan ọhun mu u jẹ gbe, nitori wọn tun le wa lati waa ṣe mii in, wọn fi aidunnu wọn han lori iṣẹlẹ ọhun, ti wọn lo ba ni lọkan jẹ pupọ.

 

Ajọ Ọlọfin Adimula tun sọ ninu ọrọ wọn pe iṣẹlẹ ibanujẹ ọhun ki i ṣe ti Ọwọ nikan bi ko ṣe gbogbo ilẹ Yoruba, wọn wa gba Ọlọwọ tiluu Ọwọ lati gba kawọn oniṣẹṣe ti wọn wa niluu rọjo epe le awọn eeyan naa lori, ki wọn si jẹ ki wọn ri ibinu awọn alaalẹ.

 

Atẹjade ọhun tun sọ pe bi wọn ṣe da ẹmi awọn alaiṣẹ yii legbodo lati ọwọ awọn afurasi Fulani,ti jẹ ka mọ pe ko sibi ti eto aabo to peye tun wa mọ nilẹ Yoruba.

 

Bẹẹ ni wọn tun wa rọ awọn Gomina ilẹ Yoruba lati pada jokoo ki wọn ronu bi wọn yoo ṣe dojuko eto aabo, ko to di pe nnkan naa yoo kọja agbara wọn.

 

Ajọ naa waa sọ pe awọn ti ṣetan lati maa lọọ kaakiri ilẹ Yoruba lati ṣe ipade pọ pẹlu awọn ọba alaye lori ọna bi wọn yoo ṣe gba awọn agbara tawọn babanla wọn n lo pada, lati fi daboobo ilu.

 

Bẹẹ ni wọn wa pari ọrọ nipa bi ba Gomina Rotimi Akeredolu, tipinlẹ Ondo ati gbogbi ilẹ Ọwọ, to fi mọ awọn mọlẹbi ti iṣẹlẹ ọhun sẹlẹ si kẹdun.


No comments:

Post a Comment

Pages