Ọlagoke rọ ajọ eleto ibo INEC lati ṣeto ibo ti ko ni mu wahala da ni - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 19 June 2022

Ọlagoke rọ ajọ eleto ibo INEC lati ṣeto ibo ti ko ni mu wahala da ni


 

Ọjọgbọn Sabit Ariyọ Ọlagoke, to ni Shafaudeen Islam, ti rọ ajọ eleto idibo INEC, lati ri i pe wọn ṣeto ibo gbogbogboo to n bọ lọdun 2023,lọna ti ko ni mu wahala tabi rogbodiyan da ni ati pe kawọn araalu gan an ri i pe wọn dibo wọn fẹni to tọ.

 

Ọkunrin naa sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita, fun ti ayẹyẹ dẹmokireesi to kọja to kọja yii, nibi to ti ki awọn araalu ku oriire ayẹyẹ ayajọ ọdun ijọba tiwa-n-tiwa, ta a mọ si dẹmọkiresi naa.

 

Ojiṣẹ Ọlọrun naa sọ pe ijijagbara awọn eeyan, nibi tawọnọmọ orileede yii ti fara wọn jin, tọpọ ẹmi ti ba a lọ, lo mu ki iru ayajọ ọhun maa waye. O wa rọ wọn ki wọn ma jẹ ki iya yii ko lọ lasan.

 

Ọlagoke tun ṣalaye siwaju pe bi wọn ṣe n ṣe iranti ayajọ dẹmọkireesi ọhun, ki wọn ma ṣe gbagbe akitiyan Oloogbe Oloye MKO Abiọla, ẹni ti gbogbo ọmọ orileede yii dibo fun lọjọ kejila, oṣu kẹfa, ọdun 1993., eyi to mu ki wọn fi ọpọ awọn ajijagbara sọgba ẹwọn.

 

O ni ki i wa ṣe ki a wa maa ṣe ayajọ dẹmokireesi yii lọdọọdun lasan bi ko ṣe lati ma ṣe jẹ ki iya tawọn akọni naa ti jẹ lọ lasan, Ọna kan ṣoṣo to ni a si fi le ṣe eyii  ni pe ki gbogbo wa jọ ṣiṣẹ pọ lati le jẹ ki aṣyọri ba ijọba tiwa-n-tiwa yii.

 

Ọjọgbọgbọn naa tun fikunọrọ ẹ pe’’ Lati le tan ka ijọba tiwa-n-tiwa yii, a gbọdọ ri pe eto idajọ rere, ki a si maa ṣe gbogbo nnakn nitunbinubi,ki a si fi apẹẹrẹ rere tawọn to wa lẹyin yoo mọọ tẹle silẹ’

 

 

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages