Lọjo ti Amosun ṣẹruba Dapọ Abiọdun l’ Abẹokuta - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 19 June 2022

Lọjo ti Amosun ṣẹruba Dapọ Abiọdun l’ Abẹokuta

Titi di akoko ta a n kọ iroyin yii, lawọn eeyan ilu Abẹokuta, si sọ nipa eto kan ti ẹgbẹ oṣelu APC, nipinlẹ Ogun, ti igun Sẹnetọ Ibikunle Amosun, ṣe fun ọga wọn yii, eyi ti wọn sọ pe o min igboro titi,koda ti wọn lo to tun da jinnijinni bo Gomina Dapọ Abiọdun.

Eto ọhun to waye ni Ake, ni awọn eeyan ti pọ rẹpẹtẹ a fi bi ẹni pe boya Senetọ Amosun, to n ṣoju ẹkun aarin gbungbun Ogun, nile igbimọ aṣofin niluu Abuja waa ṣe ipolongo ibo ni lọjọ naa

Ohun to si n jẹ ko ya awọn eeyan lẹnu ni wọn ni laarin wakati mẹrinlelogun, ni wọn ṣeto ọhun, ti ero si pọ rẹpẹtẹ bi omi, koda ṣe ni sunkẹrẹ- fakẹrẹ ọkọ waye lagbegbe ibi ti wọn ti ṣayẹyẹ ọhun.

Iyẹn nikan kọ, bi wọn ṣe pari eto ọhun ni wọn tun tẹle Amosun yika kaakiri awọn agbegbe kan niluu Abẹokuta, tawọn eeyan si n rọ lẹyin ẹ bi omi.Ibeere tawọn eeyan n beeere ni pe ṣe ipolongo ti bẹrẹ ni?

Amọ sa, Sẹnetọ Ibikunle Amosun, to ti figba kan jẹ Gomina nipinlẹ Ogun ti sọ idi to fi juwọ silẹ fun ipo aarẹ to dije fun labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, nibi ibo abẹle wọn. Nigba to n bawọn eeyan sọrọ, ọkunrin naa sọ pe erongba oun lati di aarẹ jẹ ida ogun fun orileede yii, nigba ti ida ọgọrin ẹ si jẹ tilẹ Yoruba.

O sọ pe niwọngba ti awọn ẹkun yooku wọn ti fi atilẹyin wọn han fun Aṣiwaju Bọla Tinubu, to jawe olubori nibi ibi abẹle ọhun, ko si nnkan toun le ṣe ju koun juwọ lẹ lati ṣatilẹyin fun ida ọgọrin tilẹ Yoruba.

O wa rọ awọn eeyan ipinlẹ Ogun lati ṣatilẹyin nla Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, fun ibo gbogbogboo to n bọ lọdun 2023, o ni o da oun loju pe gbogbo ipenija ta a koju nipa ọrọ aje ati aabo ni yoo dopin.

Amosun  sọ pe “Mo fẹẹ ki ẹ mọ pe diẹdiẹ bayii ni a o bori awọn iṣoro wa lorileede yii, ti Naijiria yoo si lọ sibi gga, ẹ nigbagbọ ninu mi, ẹ ẹ maa reti aabo to peye laipẹ, igba ọtun si n pada bọ’’.

Bẹẹ lo sọ pe lẹyin Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, to jẹ aarẹ orileede yii tẹlẹ, ko sẹni to tun sin ipinlẹ Ogun to oun ninu awọn to ti ṣejọba. Bakan naa ni Amosun tun ṣe abẹwo lọọ sọdọ Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ,lọjọ naa.

Lara awọn to tẹlẹ e kaakiri lọjọ naa ni Sẹnetọ Iyabọ Aniṣulowo, Agbẹjọro Biyi Ọtẹgbẹyẹ, to jẹ oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, atawọn eeyan mii in.

 


No comments:

Post a Comment

Pages