E mojuto awọn ọmọ yin lori iwọkuwọ- Ọbasanjọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 25 July 2022

E mojuto awọn ọmọ yin lori iwọkuwọ- Ọbasanjọ



Aarẹ orileede yii tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ti gba awọn obi nimọran lati maa mojuto awọn ọmọ wọn lori iwọkuwọ ti wọn maa n wọ kaakari. Nitori bo ṣe bawọn ọmọ naa loju jẹ bẹẹ naa gẹlẹ ni n doju ti awọn obi wọn pẹlu. 

Ọbasanjọ sọrọ naa ninu iṣẹ eyi ti iyawo ẹ , Iyaafin Bọla Ọbasanjọ jẹ nibi ayẹyẹ ikẹkọọ jade ati fifi ami ẹyẹ da awọn eeyan lọla fawọn akẹkọọ mẹrindinlọgọrun, tileewe giga Lyceum Group of School, to waye ni gbọngan ile ikawe Oluṣẹgun Ọbasanjọ, niluu Abẹokuta.

 

Aarẹ tẹlẹ ọhun kọkọ dupẹ lọwọ awọn obi lori ipa ti wọn ko lati ran ọmọ wọn nileewe, ki wọn le janfaaani eto ẹkọ. O wa sọ pe ẹkọ ko le pari bi wọn ko ba kọ wọn nipa wiwọ aṣọ paapaa ni gbigbogun ti iwọkuwọ lawujọ.

 

O fi aiduunu ẹ han lori bi aṣọ iwọkuwọ ṣe gbilẹ lawujọ paapaa julọ laarin awọn obinrin, ati awọn ọkunrin naa, o ni ara ainibẹru obi lo jẹ kawọn ọmọ naa maa huwa bẹẹ.

 

Ọbasanjọ waa gbawọn lamọran lati rii pe wọn yẹ ibi tawọn ọmọ wọn ko aṣọ ti wọn ba n wọ pamọ si,ki wọn si samojuto wọn titi debi pe wọn fẹẹ jade kuro nile.

O tun lo akoko naa lati fi dupẹ lọwọ awọn alakoso ileewe ọhun ti wọn tun jẹ oludasile ileewe yii Maureen Ola- Williams, lori bi wọn ṣe rii pe inura awọn ọmọ naa dun un wo loju, to si bẹgbẹ gbe.

 

O ni aimọye ẹkọ loun kọ lori imura awọn ọmọ naa lọjọ ayẹyẹ ọhun to si fihan pe wọn mu imura lọkunkundun nileewe wọn. To si ni ki wọn maa tẹsiwaju bẹẹ lọ.

 

Bakan lo tun gba awọn akẹkoo nimọran lati jẹ ọmọ rere ki wọn si ri pe ọjọ iwaju wọn ṣe pataki nibi gbogbo ti wọn lọ, ki wọn si tubọ kọju mọ won

 

No comments:

Post a Comment

Pages