Toyin Amuzu, oludije fun ipo aṣoju-ṣofin labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, fun agbegbe Abẹokuta South, ti ki Ọnarebu Ọladipupọ Adebutu, toun dije fun ipo gomina, ku oriire ti ajabọ idalare to gba nile ẹjọ giga tijọba apapọ lonii
Ninu atẹjade ti ọkunrin naa fi sita lo tun lo akoko ọhun lati fi pe gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun, lapapọ lati jọ ṣiṣẹ pọ fun aṣeyọri ibo to n bọ lọdun 2023.
Oludije ọhun tun fikun ninu ọrọ ẹ pe ki Adebutu gba abajade aṣeyọri naa gẹgẹ bi idunnu lati ọdọ Ọlọrun wa. O waa sọ pe pẹlu bi ọkunrin naa ṣe jawe olubori ninu ẹjọ ti wọn pe e naa eyi tumọ si pe gbogbo ẹjọ to wa niwaju ẹ lo ti dopin, ki itẹsiwaju maa lọ lo ku.
Ọnarebu Ọladipupọ Adebutu , oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, ni AdajọTaiwo Taiwo, tile ẹjọ giga tijọba apapọ to wa ni Abuja gba gẹgẹ bi oludije ninu ẹjọ ti Jimi Lawal pe ajọ INEC, PDP ati Ọnarebu Oladipupo.
Jimi Lawal, ti wọn jẹ oludije gomina lo gbe wọn lọọ sile ẹjọ pe ọna ti Adebutu gba di oludije ko bofinmu lori awọn wo lo yẹ ki wọn jẹ aṣoju ti wọn yoo dibo. Ṣugbọn Adajọ naa sọ ninu idajọ ẹ pe ẹjọ ti wọn pe ọhun jẹ laarin awọn ẹgbẹ oṣelu ati pe ile-ẹjọ ko le da iru ti wọn gbe wa ko le da iru nnkan bẹẹ, lo ba tu ẹjọ naa ka.
Amuzu waa pe gbogbo ọmọ ẹgbẹ PDP, lati wa ni isọkan, nitori akoko to lati le APC kuro nijọba ninu ibo to n bọ lọdun 2023.
No comments:
Post a Comment