Yayi ki Aṣiwaju ku oriire tikẹẹti ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu APC - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 9 June 2022

Yayi ki Aṣiwaju ku oriire tikẹẹti ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu APC

 

Aṣofin Ọlamilekan Adeọla, tọpọ mọ si Yayi, oludije fun ipo sẹnetọ fun ẹkun Ogun West, ninu ibo to n bọ lọdun 2023, ti ki Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ku oriire fun bo ṣe jawe olubori ninu ibo abẹle ẹgbẹ APC, fun ipo aarẹ lọdun 2023.

 

Ninu atẹjade ti Oloye Kayọde Ọdunaro, to jẹ akọwe iroyin fun ọkunrin naa fi sita, lo ti sọ pe gẹgẹ ọkan lara awọn ọmọlẹyin ẹ lati nnkan bi ogun ọdun, ko ya oun lẹnu pe Aṣiwaju ni gbogbo nnkan to fi le le mu orileede yii lọ sibi giga.

 

O sọ pe aṣeyọri ọhun ki i ṣe fun ẹgbẹ OPC nikan, gbogbo orileede yii ni to tun wa ba akoko taa n fẹẹ ki idgbasoke ba wa. O wa lo akoko ọhun lati fi pe gbogbo ọmọ Naijiria lati ṣiṣẹ pọ pẹlu atilẹyin fun Tinubu ninu ibo to n bọ lọdun 2023, ko le depo aarẹ naa, ki igbe aye idẹrun ko le baa tẹ siwaju.

 


No comments:

Post a Comment

Pages