Ṣe lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, ti agbegbe Ado-Odo/Ọta, nipinlẹ Ogun, tu yaya jade lọ si ọfiisi ẹgbẹ wọn to wa niluu Abẹokuta, lati fi ẹhonu wọn han lori ibo abẹle fun ipo aṣoju ṣofin, ti wọn ni ko waye amọ ti wọn ni wọn fi ọna ẹburu fi orukọ oludije kan si, ti wọn si fi ranṣẹ siluu Abuja.
Pẹlu oriṣiriṣi akọle ni wọn kọ si kaadi ti wọn gbe dani ti wọn fi tako iwa ti wọn lawọn olye ẹgbẹ ọhun hu, nitori bi wọn ṣe ni fẹẹ gbe Mustapha Adekunle le awọn lori.
Wọn sọ pe awọn ri gbamu pe Mustapha Adekunle, yii ni wọn fi ranṣẹ siluu Abuja, gẹgẹ bi oludije fun ipo aṣoju-ṣofin, laiṣe pe wọn dibo abẹle lati yan an.
Wọn wa fẹsun kan awọn oloye ẹgbẹ naa nipinlẹ fun iwa ti wọn hu lori bi wọn ṣe forukọ oludije ranṣẹ siluu Abuja, laijẹ pe wọn dibo yan an. Bo tilẹ jẹ pe ọpọ wakati ni lawọn oluwọde naa fi duro ṣugbọn ti alaga ẹgbẹ naa, Ọnarebu Sikirulai Ogundele, ko da wọn lohun, a figba ti ọsan pọn.
Lakooko naa lo ṣẹṣẹ waa sọ fawọn to n fi ẹhonu wọn han lati lọọ kọ iwe ẹhonu wa, ki wọn si fi ranṣẹ si ọfiisi wọn
O sọ pe ẹgbẹ oọelu ko le kan ṣiṣẹ lori ọrọ ẹnu lasan laijẹ pe o wa ni akọsilẹ., koda o ni wọn le fi sọwọ si ọfiisi wọn to wa ni Abuja pẹlu.
Bakan naa ni Ọnarebu Lẹyẹ Ọdunjọ, to jẹ igbakeji alaga ẹgbẹ ọhun naa fidi ẹ mulẹ pe loototọ, ibo abẹle Kankan ko waye lagbegbe naa fun ipo aṣoju-ṣofin. O ni awọn eeyan ọhun sọ pe awọn ti lọ si Abuja, ibẹ lawọn ti gbọ pe wọn ti forokọ ẹnikan sibẹ.
O waa gba wọn lamọran pe ki wọn ṣe suuru, ki wọn si gbe igbesẹ to ba yẹ lọna to ba ofin mu.
No comments:
Post a Comment