Ẹ sọ fun Adebutu ko ma yọ layọju- Ṣẹgun Ṣowunmi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 8 June 2022

Ẹ sọ fun Adebutu ko ma yọ layọju- Ṣẹgun Ṣowunmi


 

Oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun, Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, ti sọ pe ki Ladi Adebutu, ti wọn fun ni iwe ẹri oludije gomina ko ma tii yọ layọju.

 

Ninu ọrọ kan to gbe jade lori ẹrọ ibanidọrẹ lo ti sọ pẹlu gbogbo bi ọrọ naa ṣe wa nile-ẹjọ, wọn tun le gbe igbesẹ lati fun ẹnikan ni kaadi, asiko ọrọ ko tii to. O sọ pe ki wọn beere lọwọ wọn ibi ti wọn ba iru nnkan bẹẹ ti wọn ṣe lọdun 2011, 2015 ati 2019, o ni ofo ni wọn mu bọ nibẹ.

 

Ṣowunmi waa ni ki Adebutu ma ti yọ layọju,titi ti idajọ ile-ẹjọ yoo fi waye, igba akọkọ ree, to ti n fidijanlẹ. O ni ki awọn eeyan ẹ farabalẹ.  O ṣapejuwe ti APC ni Zamfara, Nipinlẹ Rivers, O ni wọn ko ni oludije kankan nigba tawọn naa ṣeru ẹ, irufẹ bẹẹ lo ni o n bọ nipinlẹ Ogun naa, ti wọn ko ba sọra.

 


No comments:

Post a Comment

Pages