Gọngọ sọ lọjọ ti Adeyẹmi gba tikẹẹti oludije gomina labẹ Action Alliance - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 7 June 2022

Gọngọ sọ lọjọ ti Adeyẹmi gba tikẹẹti oludije gomina labẹ Action Alliance


 

Lọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii, ni ẹgbẹ oṣelu Action Alliance, AA, fun Dokita Olufẹmi Adeyẹmi ni tikẹẹti gẹgẹ bi oludije wọn fun ipo gomina ninu ibo to n bọ lọdun 2023. Bẹẹ lọkunrin naa ti ṣeleri pe oun ko ni ja ipinlẹ Ogun ni tan an mọ, bi wọn ba le dibo yan oun wọle.

Nibi eto ibo ọhun to waye ni ọfiisi ẹgbẹ ọhun to wa ni Ijẹja, niluu Abẹokuta, nibi ti aṣoju awọn eleto idibo lorileede yii ti wa nibẹ ni ọkunrin yii ti jawe olubori laini alatako kankan.

Nigba to n sọrọ lẹyin ti wọn fa ọwọ ẹ soke gẹgẹ bi oludije wọn, Dokita Adeyẹmi, to tun jẹ oluṣiro agba ati agbẹjọro nla ṣeleri pe gbogbo ọna loun yoo gba lati mu ayipada rere ba ipinlẹ Ogun.

O ṣeleri pe gbogbo iya ti wọn fi jẹ awọn oṣiṣẹ-fẹyinti ni yoo dopin toun da dori aleefa ati pe oun ko ni fi owo oṣu jẹ awọn oṣiṣẹ ijọba niya bẹẹ lo ni idagbasoke rere yoo tun de ba awọn igberiko wa gbogbo.

Oludije ọhun sọ pe ibo tawọn n wa lati di gomina ko ju ẹgbẹrun lọna ọọdunrun lọ, toun si mọ pe lagbara Ọlọrun, awọn araalu yoo dibo ọhun foun, Bakan naa lo sọ pe eto ẹkọ, ilrea ati ọna rere jẹ oun logun, nitori irọrun araalu, lo jẹ oun logun.

Ko to to akoko ọhun ni, alaga fẹgbẹAA, nipinlẹ Ogun, ti dupẹ lọwọ Ọlọrun fun akoko naa, o sọ pe igba akọkọ ree ninu itan ẹgbẹ yii ti wọn yoo ni oludije fun ipo gomina nipinlẹ naa.

Bẹẹ lo tun fikun ọrọ ẹ pe ko to di pe awọn ṣe ibo abẹle ti gomina yii lawọn ti kọkọ ṣe tawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin, atawọn yooku, to si sọ pe awọn ti gbaradi fun ibo to n bọ ọhun.

O ni ki pe eeyan n ṣe iyemeji, ẹgbẹ Action Alliance ni yoo jawe olubori ninu ibo to n bọ lọdun to n bọ yii. O wa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ lati ṣatilẹyin to jọju fawọn oludije wọn gbogbo.

Ọnarebu Adeyẹmi, to jẹ agba ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun, lo fa ọwọ oludije naa soke pẹlu alaga ẹgbẹ wọn lẹyin ti wọn ti panupọ yan ọkunrin naa.

 


No comments:

Post a Comment

Pages