Irọ ni wọn pa o, ko si ẹsun kankan ti wọn fi da Yayi duro o- Ọdunaro - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 29 May 2022

Irọ ni wọn pa o, ko si ẹsun kankan ti wọn fi da Yayi duro o- Ọdunaro


 

Ko to di pe ibo abẹle sipo aṣofin waye ni gbọngan Oronna, nilu Ilaro, ni oriṣiriṣi awuyewuye ti n lọ labẹlẹ pe awọn igun to n ba Sẹnetọ Adeola Ọlamilekan, tọpọ mọ si Yayi, Iyẹn Ṣẹnetọ Tolu Ọdẹbiyi ti gba ile-ẹjọ kan lọ niluu Abẹokuta, ti wọn si ti da Yayi duro lati ma ṣe kopa.

 

Iroyin ọhun tan ka, ti wọn nitori ẹ ni Sẹnetọ Ọdẹbiyi ṣe n sọ pe oun ti wọle laini alatako kankan ṣugbọn ni bayi, wọn tio sọ pe ko si ootọ ninu ọrọ naa ati pe ko sile-ẹjọ to da Yayi duro ninu ibo to waye ẹhun, nibi ti wọn ti kede ẹ pe gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori.

 

Oloye Kayọde Ọdunaro, to jẹ alakoso akọwe iroyin fun Ṣẹnetọ Adeọla, lo sọrọ ọhun  ninu atẹjade kan to fi sita lati fi tako ahesọ ọrọ ọhun.Gẹgẹ bo ṣe wi, ko si iwe ipẹjọ kankan to tako oludije tuntun fun ipo aṣofin fun ẹkun Ogun West, niluu Abuja,  labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ninu ibo to n bọ lọdun 2023 naa.

 

O sọ pe o yẹ ki wọn la gbogbo awọn to n gbe igbekugbe nipa ipẹjọ ọhun lọyẹ, pe ti iru nnkan bẹẹ ba waye, o gbọdọ ni adajọ, ti yoo gbọ ẹjọ naa, ti yoo si gbe ipinnu jade, to si sọ pe iru nnkan bẹẹ ko waye.

 

O waa sọ pe ti nnkan ti wọn sọ ba jẹ ootọ, ki wọn darukọ adajọ to fun wọn nidajọ, o ni o ṣeeṣe ko ma jẹ pe wọn yi iwe ipẹjọ ọhun ni to si le fa wahala si wọn lẹsẹ ti akoko ba to.

 

Ọdunaro wa lo akoko naa lati sọ fun gbogbo ọmọ Ogun West, pe ki wọn ma tẹti si isọkusọ ọhun, nitori o yẹ ki wọn mọ pe ẹni ti wọn ba na ni ara n ta.

 


No comments:

Post a Comment

Pages