Ṣẹnetọ Tolu Ọdẹbiyi gbe Yayi lọ sile ẹjọ lo ba ni oun loun jawe olubori ibo aṣofin fun Ogun West - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 28 May 2022

Ṣẹnetọ Tolu Ọdẹbiyi gbe Yayi lọ sile ẹjọ lo ba ni oun loun jawe olubori ibo aṣofin fun Ogun West

 

Mariam Gbadamọsi

 

Sẹnetọ Tolu Ọdẹbiyi, to n ṣoju agbegbe Ogun West, ti sọ pe ariwo lasan ni gbogbo eyi ti wọn n pa Sẹnetọ Ọlamilekan Adeọla, tọpọ mọ si Yayi, lo jawe olubori ibo aṣofin ti wọn di niluu Ilaro, o ni oun loun loun bori ibo abẹle ọhun.

 

Ohun ta a gbọ ni pe ki ibo ọhun to waye ni Sẹnetọ Tọlu ti gbe Yayi lọ sile ẹjọ, ti wọn si sọ pe ile ẹjọ ti da ọkunrin naa duro lati ma ṣe kopa, idi niyii ti Ọdẹbiyi fi n pariwo lakooko to n ba awọn oniroyin sọrọ pe oun loun jawe olubori

 

 O sọ pe oun jawe olubori laini alatako kankan, nitori awọn tawọn jọ dije fun ipo ọhun iyẹn Gboyega Nasir Isiaka ati Abiọdun Akinlade ni wọn ti juwọ silẹ ti wọn si ti dijre fun ipo mii-ii.

 

Sẹnetọ ọhun tun sọ pe’’ Gbogbo ogo lo jẹ ti Ọlọrun, lori bi oun ṣe jawe olubori laini alatako Kankan, eyi to si ti wa ninu itan Ogun West labẹ ẹgbẹ oṣelu APC. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ibo abẹle ọhun pe emi nikan ni mo wọle ni alatako awọn eeyan mi meji yooku Gboyega Nosiru Isiaka ati Akinlade Abiọdun, ti gba tikẹẹti aṣoju-ṣofin ni ti wọn.

 

 

Ọkunrin yii wa gboriyin fawọn agba ẹgbẹ naa ni Ogun West atawọn oloye ẹgbẹ fun bi wọn ṣe pada tun dibo fawọn.

 

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages