Ibo kan ṣoṣo ti wọn di fun Ọtẹgbẹyẹ tawọn to ṣeto ibo wọgile da wahala silẹ. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 27 May 2022

Ibo kan ṣoṣo ti wọn di fun Ọtẹgbẹyẹ tawọn to ṣeto ibo wọgile da wahala silẹ.

 

Bi nnkan ṣe n lọọ yii afaimọ ki ibo kan ṣoṣo ti wọn di fun Biyi Ọtẹgbẹyẹ, nibi ibo abẹle ẹgbẹ oṣelu APC, to waye ni papa iṣere MKO Abiola , Abẹokuta, tawọn to ṣeto ibo ọhun fagile ma da wahala silẹ, nitori wọn ti n wọdi awọn eeyan naa idi ti wọn fi ṣe bẹẹ.

 

Ibo ọhun to waye nibi ti orukọ awọn oludije mẹfa ti kopa, awọn naa ni Biyi Ọtẹgbẹyẹ, Rẹmi Bakare, Mọdele Ṣarafa, Adekunle Akinlade, Owodunni Ọoayẹmi ati Dapọ Abiọdun.

 

Dapọ Abiọdun , ni wọn  kede gẹgẹ bi olujawe olubori nibi ibo ọhun tawọn aṣoju ti kopa lawọn ijọba ibilẹ ogun pẹlu ibo ẹgbẹrun kan  ati ọgọjọ le ni mẹjọ, tawọn yooku ko si ni Kankan yatọ si ti Ọtẹgbẹyẹ ti wọn fagile

Awọn to n ka ibo naa ni wọn ti kọkọ darukọ seti gbogbo aye pe Ọtẹgbẹyẹ ni ibo kan ṣoṣo lati ijọba ibilẹ Ipokia, ṣugbọn ti wọn yi ohun pada, ti wọn lawọn fagile lai sọ idi ti wọn fi ṣe bẹẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, bi awọn oluṣeto ibo ọhun  ṣe kede ibo Ọtẹgbẹyẹ ni wahala de ba awọn to eeyan Gomina Dapọ Abiọdun, loju ẹsẹ ni ẹni to ka ibo ọhun ba sọ pe ọrọ ko ri bẹẹ mọ, ti wọn si sọ pe gbogbo awọn oludije yooku ko ni ibpo kankan.

Ohun ti wọn sọ tẹlẹ ni pe ninu ibo ọgọta Ipokia Dapọ Abiọun ni mọkandinlọgọta, nigba ti Ọtẹgbẹyẹ ni ẹyọ kan ṣoṣo, Ṣugbọn nibi gbogbo awọn yooku ni Dapọ ti ko gbogbo ibo wọn.

Ọpọ awọn to si gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun ni wọn sọ pe oun aburu gba a ni wọn hu lọjọ naa, afi bi eedi lo si jẹ fun wọn pẹlu, amọ ibi tọrọ naa yoo yọri si bayii ko sẹni to le sọ.

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages