Ẹgbẹ oṣelu Lebọ ipinlẹ Ogun ṣeto ibo abẹle fun ile igbimọ aṣofin - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 27 May 2022

Ẹgbẹ oṣelu Lebọ ipinlẹ Ogun ṣeto ibo abẹle fun ile igbimọ aṣofin


Lọjọbọ, Tọsidee. Ana, ni ẹgbẹ oṣelu Lebọ tipinlẹ Ogun,  ṣeto ibo abẹle fawọn oludije wọn fun ipo ọmọ ile igbimọ aṣofin, ti yoo kopa nibi ibo gbogbogboo lọdun to n bọ

Gbọngan iwe-iroyin, niluu Abẹokuta ni eto ọhun ti waye, nibi ti wọn ti dibo yan awọn mẹrindinlọgbọn gẹgẹ bi oludije wọn, eyi ti Kọmureedi Abayọmi Arabambi ati Bọde Simeon ti ṣoju ẹgbẹ lapapọ,ti Onimọ-Ẹrọ Feyiṣọla Oluṣẹgun Micheal si jẹ alaga igbimọ to ṣeto ibo ọhun.

Awọn yooku ti wọn tun jọ ṣeto ibo ọhun ni Ọlaniyi Ṣobayọ toun jẹ akọwe nigba ti Alaaji Adegbitẹ si jẹ ọmọ ẹgbẹ. Ninu ọrọ alaga igbimọ eto ibo ọhun, o sọ pe awọn ṣeto ibo abẹle naa pẹlu adehun lati ọdọ awọn oludije yii.

 

Awọn to jawe olubori gẹgẹ bi oludije ọmọ ile igbimọ aṣofin naa ni Salam Bashir Tẹniọla, fun Abeokuta North, Adewale Adekunle ati Abọlade Ọlatunde, fun ẹkun Abeokuta 1 ati 2

Temiloluwa Ọmọlola Alarape ati Adelokiki Ọlatokunbọ Ọlatunbosun ni wọn jawe olubori fun Ado-Odo Ọta migba ti  Adebiyi Olumuyiwa Adekunle wọle fun agbegbe Ewekoro.Ibrahim M. Taofeeq ati Aina Taiye Ganiyu jẹ ti Ifọ, Bukọla Ogunde, yoo ṣoju Ijebu East, Bello Quazeem Oluwaseun, Adekoya Adelaja Adewale, ni  Ijẹbu North, I & II, Ijebu North East, Oliseh - Samuel Elisabeth Temidayọ, Ijebu North East, Kolawole Olusola John, Ijebu-Ode ati  Ṣobọwale Babatunde Adewunmi, jẹ oludije wọn ni  Ikenne.Fun agbegbe Imeko - Afon, Quadri Esther Olutayo, Ipokia, Aderohunmu Azeez Olaitan, Obafemi Owode, ni Juliana Andrew, Odẹda, Ṣojobi Adeṣina Wasiu, Odogbolu, Adebola Abisọla Funmilayo, Ogun Water Adetoun Adesanya ati Side Mobolaji Omotunde, Remo North, Okusanya Oyewale Kayode, Ogunniyi Sunday Toluwalope for Sagamu I & II, Olaleye Mubarak Ayinde ati Olajide Amusan for Sagamu I & II ati Adeleye Godwin Kayode jẹ oludije wọn fun Yewa South.


Awọn to jawe olubori yii ni yoo figagbaga pẹlu awọn oludije ninu ẹgbẹ oṣelu yooku nibi ibo ọdun 2023 ọhun

 


No comments:

Post a Comment

Pages