Ibọn ni wọn fi n le awọn eeyan nibi ibo abẹle awọn Adebutu PDP l’ Abẹokuta - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 26 May 2022

Ibọn ni wọn fi n le awọn eeyan nibi ibo abẹle awọn Adebutu PDP l’ Abẹokuta


Fun bi aimọye iṣẹju ni ọta ibọn fi n ro kikan kikan, ni gbọngab Ọbasanjọ Library, l’Abẹokuta, lalẹ Ọjọruu, Wẹside, lakooko ti ibo abẹle tawọn ti Ladi Adebutu, tẹgbẹ oṣelu PDP, n waye.

Bo tilẹ jẹ pe ko to to akoko naa, ni iru ibo yii ti waye lọgba awọn oniroyin, Iwe-Iroyin, nibi ti wọn ti kede Ṣegun Ṣowunmi, gẹgẹ bi oludije fun ibo abẹle ọhun, ṣugbọn nitori  wahala to n a waye laarin wọn lo mu ki awọn Adebutu ati JM K Lawal, naa tun ṣe ti wọn lọtọ.

Ibo to yẹ ko ti waye ni aarọ lo jẹ pe ọwọ alẹ ni wọn to bẹrẹ, nnkan ti wọn si n sọ ni pe wọn ko tii ko iwe ti wọn yoo fi dibo de. Bakan naa, ẹni to ba ri awọn aṣoju ti wọn fẹẹ wa dibo yoo ti mọ pe ija ni ọpọ wọn ba wa si ọhun.

Ohun to si fa a gẹgẹ bi a ṣe gbọ ni pe wọn ni wọn ko forukọ awọn aṣoju kan sinu iwe ti wọn yoo ti dibo ati pe tawọn ti Adebutu nikan ni wọn ko sinu iwe ọhun.

Ọrọ ta a n sọ yii lagbara debi pe awọn ọlọpaa ko fẹẹ ka awọn eeyan ọhun, ti wọn si fẹẹ fi dandan wọle sibi ti wọn ti fẹẹ dibo ọhun,pẹlu gbogbo ẹ ṣe  lawọn aṣoju ọhun yari kanlẹ.

A tun gbọ pe nigba ti agbara awọn ọlọpaa ko kaa mọ ni wọn ranṣe pe awọn ṣoja, tawọn yẹn bẹrẹ si nii yinbọn soke, tawọn eeyan to wọ nibẹ si n sa asala fẹmi ara wọn.

Lẹyin eyi ni wọn to jẹ kawọn aṣoju maa wọle amọ sibẹ naa wahala si wa nitori wọn ni gbogbo awọn to wọle ko si aṣoju ti JMK Lawal, toun naa dije nibẹ ninu wọn, eyi ti wọn lo mu fi binu sa lọ.

Nigba ti wọn pari ibo naa ni wọn kede Adebutu gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori lọdọ ti igun ti wọn ni oludije gomina ba di meji. 


No comments:

Post a Comment

Pages