Lẹyin ti wọn dibo yan an gẹgẹ bi oludije gomina; Ṣẹgun Ṣowunmi lọọ dupẹ ni ṣọọṣi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 26 May 2022

Lẹyin ti wọn dibo yan an gẹgẹ bi oludije gomina; Ṣẹgun Ṣowunmi lọọ dupẹ ni ṣọọṣi



 

 

Laarọ kutu owurọ yii, ni oludije to ṣẹṣẹ jawe olubori lati dije labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, lọọ jọsin lati dupẹ lọwọ Ọlọrun lo bo ṣe ṣaṣeyọri ninu ibo to waye lọjọ Wẹsidee, ọsẹ yii.

 

Lẹyin to fi ẹmi imoore ẹ han si Ọlọrun tan, lo tun lo akooko naa lati ki Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ,to si fi abọ jẹ fun un.

 

Ninu ibo ọhun to waye ninu ọgba awọn oniroyin, iyẹn Iwe Iroyin, l’Abẹokuta, nibẹ ni wọn ti kede Ṣẹgun Ṣowunmi, ẹni to ti figba kan jẹ olupolongo aarẹ fun Atiku Abubakar, lọdun 2019, gẹgẹ bi olujawe olubori fun ibo abẹle ẹgbẹ oṣelu PDP, to waye ọhun

 

Nigba to n sọrọ lọjọ naa, Ṣowunmi dupẹ lọwọ awọn olori ẹgbẹ lapapọ, atawọn aṣoju fun bi wọn ṣe dibo yan oun lati dije lorukọ ẹgbẹ naa fun ibo gomina ti yoo waye lọdun 2023.

 

O waa ṣeleri pe oun ko ni jawọn ni tanmọ ati pe  oun fẹẹ atilẹyin lati ri pe wọn jawe olubori ninu ibo gbogbogboo to n bọ lọna naa.

 


1 comment:

  1. Oní Yẹ̀yẹ́ ènìyàn 😄😄😄

    ReplyDelete

Pages