Aarẹ fẹgbẹ awọn Oodua People’s Congress (OPC), Ọtunba Wasiu Afọlabi, ti rọ gbogbo awọn Gomina ilẹ Yoruba lati pamọ pọ pe apero pajawiri laarin awọn eleto aabo, lati le tete wa ọna abayọ si bi wọn ṣe n da ẹmi awọn eeyan legbodo.
Ninu atẹjade ti ọkunrin naa fi sita loti sọrọ naa lati fi aidunnu ẹ han lori bawọn kan ṣe pa awọn ogoji eeyan nibi ti wọn ti n jọsin nile ijọsin Saint Francis Xavier Catholic Church,to wa niluu Ọwọ, nipinlẹ Ondo.
Aarẹ ẹgbẹ naa sọ pe iṣẹlẹ yii jẹ eyi to ba ni lọkan jẹ gidigidi, eyi to fihan pe eto aabo wa mẹhẹ nilẹ Yoruba. O ni nitori idi eyi apero nla gbọdọ waye nibi tawọn eleto aabo ni ẹlẹkajẹka yoo ti jokoo lati wa ojutu si idaamu nla yii.
Bakan naa lo tun lo akoko naa lati sọ pe awọn ṣatilẹyin fun Babajide Sanwo-Olu, Gomina ipinlẹ Eko lori igbesẹ to gbe lati fofin de awọn ọlọkada,ki awọn Hausa si rii pe awọn nikan kọ ni wọn n wa ọkada lawọn agbegbe ọhun. Bẹẹ lo ni iru ofin bẹẹ naa ti waye nipinlẹ Kano ati Abuja, ti ko si si nnkan to ṣẹlẹ.
Afọlabi tun sọ pe OPC ko ni le maa wo kawọn Hausa maa doju ija kọ awọn ọlọpaa ni iru eyi ti wọn sọ pe o n waye ni Mile 2-Festac ati Idi-Araba axis. Wọn ni awọn eeyan Iwọ oorun to n gbe nilẹ Hausa, wọn ki I pa ida wọn loju, ti wọn si maa n bọwọ fun ofin ilẹ wọn, nitori idi eyi kawọn naa ṣe bẹẹ pẹlu, ẹni ti ko ba si tẹ lọrun le gba ilu ẹ lọ.
No comments:
Post a Comment