Ọrọ ẹnu kọ Ahmed Tinubu koju oṣuwọn lati di aarẹ orileede yii- OPC New Era - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 11 June 2022

Ọrọ ẹnu kọ Ahmed Tinubu koju oṣuwọn lati di aarẹ orileede yii- OPC New Era


 

Oloye Rasak Arogundade, aarẹ fẹgbẹ Oodua Peoples Congress, New-Era, ti sọ pe ọrọ ẹnu kọ Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu koju oṣuwọn lati di aarẹ orileede yii, ti igbagbọ si  wa pe yoo depo ọhun ninu ibo to n bọ lọdun 2023.

 

Ọkunrin naa sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita lati fi ki Tinubu ku oriire fun bo ṣe jawe olubori ninu ibo abẹle ẹgbẹ oṣelu APC, to waye niluu Abuja lapẹ yii.

 

O ṣapejuwe ẹ gẹgẹ bi eyi to tọ si nitori awọn ipa to ti ko nibẹrẹ pẹpẹ igba to ti wa ninu ẹgbẹ oṣelu Alliance for Democracy [AD], titi di akoko yii, eyi to jẹ ki orukọ ẹ tubọ fi di ilu mọ ọn ka.

 

Aarẹ ẹgbẹ OPC New-Era tun fikun ninu atẹjade naa pe loootọ lawọn mọ pe ki i ṣe nnkan kekere ati ipenija nigba ti ifikunlunkun n lọ lọwọ amọ awọn baa dupẹ pe o jawe olubori nigbẹyin.

 

Wọn pẹlu bo ṣe gomina ipinlẹ kan, o lo agbara ẹ lati jẹ ki ijọba tiwa-n-tiwa tan an kakiri gbogbo agbaye nipasẹ nini awọn lẹyin ti wọn ko le sẹ ẹ titi lae fun ipa to ko ninu igbe aye wọn.

 

Nigbẹyin wọn tun ba iyawo Tinubu iyẹn Sẹnetọ Rẹmi Tinubu naa yọ ayọ oriirire tikẹẹti oludije ipo aarẹ naa pẹlu adura pe lọdun to n bọ Aṣiwaju ni yoo wọle nibi ibo gbogbogboo to n bọ lọdun 2023.

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages