Oriire de! Ileefowopamọ Advans fẹẹ ya awọn obi lowo sanwo ileewe awọn ọmọ wọn - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 15 June 2022

Oriire de! Ileefowopamọ Advans fẹẹ ya awọn obi lowo sanwo ileewe awọn ọmọ wọn





Nitori bi eto ọrọ aje orileede yii ṣe ri, eyi to fa a ti ọpọ obi ko fi rowo ileewe awọn ọmọ wọn san deede mọ, Ileefowopamọ alabọọde kan, Advans Lavayete Microfinance Bank, ti ṣeleri lati maa ya awọn obi lowo lati maa fi sanwo ileewe awọn ọmọ wọn.

Nibi ipade kan ti wọn ṣe pẹlu awọn oludasilẹ ileewe aladaani atawọn obi to lọmọ nileewe  ni wọn ti ṣeleri naa laduugbo Bodija, nIbadan, lọjọ Ẹti, Furaidee to kọja.

Bakan naa ni wọn rọ awọn araalu lati ri i daju pe ẹni to ba mọ riri eto ẹkọ ni wọn dibo yan sipo aarẹ orileede yii lasiko idibo gbogbogboo ọdun 2023.

Gẹgẹ bi aludari eto karakata fun ileeṣẹ naa, Abilekọ Ademarati Oluṣayọ ṣe sọ, "eto ọrọ aje orileede yii ko fara rọ, ọpọ obi lo maa nira fun lati ri owo ileewe awọn ọmọ wọn san, to si n ṣoro fawọn to da ileewe silẹ naa lati rowo na sori okowo wọn. 

"Idi ree taa ṣe gbe eto ẹyawo yii kalẹ lati jẹ ki awọn araalu maa ri bukaata eto ẹkọ awọn ọmọ wọn gbọ.

"Ijọba Naijiria ko tun pataki eto ẹkọ. Iyẹn lo fa iyanṣẹlodi awọn olukọ yunifasiti ijọba kaakiri orileede yii. Idi ree ti awa ọmọ orileede yii ṣe gbọdọ fara balẹ gbe erongba awọn to n dupo aarẹ yẹwo daadaa ki wọn ri i pe ẹni to ba pataki eto ẹkọ ni wọn dibo wọn fun lati di aarẹ orileede yii ninu idibo ọdun to n bọ".

Nigba to n ṣalaye pataki eto ẹyawo ileeṣẹ naa fawọn araalu, Abilekọ Elizabeth Adetayọ, to jẹ adari eto iṣuna ati eto iṣọwọṣiṣẹ ileeṣẹ Advance, sọ pe "ẹni to ba ti ya owo kan tẹlẹ ti ko tii san a tan tun le ya omi-in nigba ti bukaata tuntun ba yọju. Bakan naa la maa n ba awọn obi ṣi akanti fun eto ẹkọ awọn ọmọ wọn."

Ọkan ninu awọn onibaara Advans, Ẹnjinia Adeṣina Simeon (Modesty), to jẹ gbajumọ oniṣowo mọto n'Ibadan, rọ awọn ayani-lowo naa lati maa ṣeto akanṣe ẹdinwo fawọn to ba n ya owo pupọ lọwọ wọ

No comments:

Post a Comment

Pages