Yayi ni akọsilẹ GNI ninu oṣelu buru jai, ẹnu ẹ ko gbọrọ rara. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 5 May 2022

Yayi ni akọsilẹ GNI ninu oṣelu buru jai, ẹnu ẹ ko gbọrọ rara.

 Oko ọrọ ni Sẹnẹtọ Ọlamilekan Adeọla, tọpọ mọ si Yayi fi ranṣẹ si ọkan lara awọn ti wọn jọ n dije dupo sẹnẹtọ fun Ogun West, nile igbimọ aṣofin, niluu Abuja, iyẹn Ọmọọba Gboyega Nasir Isiaka, ti wọn pe apejẹ ni GNI, nigba to ni ti gbogbo eeyan yoo ba tiẹ maa sọrọ ki i ṣe iru ọkunrin naa to jẹ pe akọsilẹ ẹ nidii oṣelu buru jai, fun bo ṣe fidi rẹmi lẹẹmẹta le rawọn lakooko to n dije fun ipo gomina.

 

Ninu atẹjade ti Oloye Kayọde Ọdunaro, to jẹ akọwe iroyin fun Yayi, fi sita, o ni nnkan ti GNI ko mọ, oun gbọdọ fi ye gẹgẹ bi ẹni to ni iriri nidii oṣelu ju lọ, o ni wọn ki i jawe olubori nitori pinpin owo, bi ko ṣe iwa ati iṣẹ takuntakun ti oludije ọhun ba ṣe.

Yayi fesi ọrọ yii lati fi sọrọ lori nnkan ti wọn ni GNI sọ ninu iwe iroyin oloyinbo kan nibi to ti fẹsun kan Yayi pe oṣelu pinpin owo kaakiri lati fi mu awọn eeyan mọlẹ ni ọkunrin naa n ṣe. Ati pe nnkan to ni o ṣe lo tun fẹẹ gbe wọ Yewa.

Ṣugbọn oju ti Yayi loun fi wo ọrọ ti GNI sọ ni bi ẹni ti lakaaye ẹ ko to ninu oṣelu, nitori ka ni o ni iriri nidii oṣelu, ko ni maa sọ iru nnkan bẹẹ jade fẹni to jẹ pe igba marun-un ọtọọtọ lo ti jawe olubori ninu ibo.

O ni aṣiiri bi oun ṣe jawe olubori awọn ibo ọhun ko ṣe lẹyin ihuwasi oun pẹlu awọn eeyan, toun ṣi ṣe daadaa ninu lori ipo ti wọn dibo yan oun si ọhun.

 

O waa gba Isiaka nimọran lati lọ kọ bi wọn ṣe n jawe olubori ninu ibo, ki i ṣe nipa pinpin owo.

 


No comments:

Post a Comment

Pages