Oloye Samson Abiọdun Odupitan, to nileeṣẹ okoowo ‘Radiation Investment Limited’’ to tun jade fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Action Alliance, iyẹn AA, ti sọ pe ti wọn ba fun oun ni oore-ọfẹ lati wọle fun ipo naa lọdun 2023, gbogbo ọna loun yoo gba lati fi kọkọrọ toun ni fi silẹkun ọna abayọ sawọn isoro to n koju orileede yii.
Ọkunrin naa sọrọ yii niluu Abuja, lakooko to n fi erongba ẹ han fawọn ọmọ ẹgbẹ naa lati jade fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu AA, O sọ pe akoko ti to bayii fawọn araalu lati gba akoso, to si da oun loju pe akoso ayọ ni yoo jẹ nigbẹyin.
Oloye Abiọdun sọ pe gẹgẹ bi a ṣe mọ oṣelu, ko yẹ ko jẹ pe awọn araalu ni, wọn ko nii maa jẹ mundunmundun ijọba, nitori ẹ si ni oun ṣe jade lorukọ awọn to ku- diẹ -kaato nigboro, lati rii pe ìṣẹ́ ati ìyà di ohun igbagbe lawujọ wa lorileede yii.
Oludije fun ipo aarẹ naa tun sọ pe’’ Bi a ba foju inu wo,ọpọ awọn nnkan ta a n ri, lo jẹ pe a le koju pẹlu ọpọlọ pipe, nitori owo ta a n gbe lori ijọba ti pọju, o si yẹ ki a wa ọna lati pese iṣẹ fawọn ọmọ wa nitori ọjọ iwaju’’
Bakan naa lo tun sọ pe bi wọn ba le jẹ ki erongba lati di aarẹ di mimuṣẹ, oun yoo pese ileeṣẹ kan ti yoo nii ṣe pẹlu awọn eeyan agbegbe, nitori ijọba apapọ jinna sawọn to n gbe lagbegbe.
Oloye Odupitan tun fikun ọrọ ẹ pe adorikodo ni wọn ṣe ọrọ ọgbin lorileede yii, amọ bi wọn ṣe lọna to yẹ gbogbo awọn araalu ni yoo janfaani ẹ.
Bẹẹ lo tun mẹnuba eto aabo, o sọ pe o jẹ ẹdun ọkan lori bi wọn ṣe mu eto abo lorileede yii, o ni ko digba ti wọn ba to pariwo sita, ko to di pe wọn fopin sii.
O ni ‘’ Mo ni awọn ọna kan lai pariwo ta a fi le koju awọn afẹmi eeyan sofo yii, amọ inu mi lo wa, mi o le sọ bayii.’’
O waa bẹbẹ fun ifọwọsowọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu AA lati le ṣatilẹyin fun un lori ipinnu ẹ, ti wọn ba fun ni tikẹẹti.
No comments:
Post a Comment