Adebutu ti fẹẹ ba ẹgbẹ PDP Ogun jẹ o—Awọn ọmọ ẹgbẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 3 May 2022

Adebutu ti fẹẹ ba ẹgbẹ PDP Ogun jẹ o—Awọn ọmọ ẹgbẹAwọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, ti ẹka Abeokuta South, nipinlẹ Ogun, ti ke si awọn olori wọn lapapọ niluu Abuja, lati gba wọn lọwọ Ọnarebu Ladi Adebutu,ọkan lara oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu naa, lori bo ṣe fẹẹ fọ ẹgbẹ ọhun nipa ji jẹ gaaba le wọn lori.

Ọrọ yii waye lakooko ti wọn ṣe iwọde wa si ọfiisi ẹgbẹ naa to wa niluu Abẹokuta,lati fi ehonu wọn han lori yiyan awọn aṣoju ti wọn ṣe lọjọ Abamẹta, to kọja yii ti wọn si sọ pe ko tẹ awọn lọrun.  

Gẹgẹ bi  ọrọ ti Idris Taiwo Ọlabọde, ọkan lara awọn oluwọde naa ba awọn oniroyin sọ, lo ti fi aidunnu ẹ han sawọn nnkan to ṣẹlẹ nibi ipade gbogbogboo, ti wọn ṣe naa.

O sọ pe o jẹ ẹdun ọkan fawọn lori awọn ti wọn yan lati waa seto ibo ipade gbogbogboo ọhun ṣe kọ lati gba abajade ibo naa wọle, ti wọn si fẹẹ gba eyi ti Adebutu ti kọ orukọ awọn kan silẹ, laiṣe pe wọn dibo yan wọn wọle, o ni o jẹ eyi to ba ni lọkan jẹ pupọ.

Ọkunrin naa sọ pe bawo ni awọn oluṣeto ọhun, ti wọn ni Ladi Adebutu gba si ootẹli Baba ẹ, to wa ni Park Inn, l’Abẹokuta, ti wọn jọ jẹ, ti wọn jọ mu, ṣe le kọ idibo ibi tawọn aṣoju eleto idibo wa nibẹ, ti wọn si ṣe gbogbo nnkan lọna to ba ofin mu.

O sọ pe ‘’ A fẹẹ ki Adebutu atawọn eeyan ẹ mu ẹri ibi ti wọn ba ti dibo jade, amọ awọn eeyan kan wa ti wọn ṣe ipade gbogboo, tawọn ajọ eleto idibo, awọn agbofinro wa nibẹ, ti ẹri ẹ si wa. Sugbọn tawọn oloye ẹgbẹ lapapọ wa n wa ọna lati ma gbaa wọle.

O sọ pe nnkan ti eyi tumọ si ni pe Ladi Adebutu, n wa ọna lati fi awọn ti wọn ko mọ jẹ gaaba le awọn lori,wọn ni ọo ṣe ṣe kaakiri ijọba ibilẹ nipinlẹ Ogun niyẹn.

Lori ipa ti alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun, Ọnarebu Sikirulai Ogundele, ko lori ọrọ yii, o sọ pe ọkunrin naa ṣe daadaa lati yanju ọrọ naa, amọ nnkan toun ri si ni ṣe ni awọn oloye ẹgbẹ nipinlẹ naa atawọn ti wọn ni ki wọn ṣeto ipade gbogboo naa, jọ fọwọsowọpọ ni.

Ọkunrin yii wa sọ pe  nnkan tawọn n fẹ ni pe ki awọn tawọn yan ko ṣe tẹwọgba.Ki wọn fọwọ si, nitori titi di akoko yii, wọn ko tii ṣe e. Ki wọn si darukọ gbogbo wọn faye sita.


No comments:

Post a Comment

Pages