Oludije Gomina fẹgbẹ oṣelu AA nipinlẹ Ogun bawọn Musulumi ṣajọyọ ọdun itunu awẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 1 May 2022

Oludije Gomina fẹgbẹ oṣelu AA nipinlẹ Ogun bawọn Musulumi ṣajọyọ ọdun itunu awẹ

Dokita Samuel Adeyẹmi, oludije gomina fẹgbẹ oṣelu Action Alliance, A A, nipinlẹ Ogun,  ti ba gbogbo awọn Musulumi ṣajọyọ ayẹyẹ ọdun itunnu awẹ ti wọn ṣe lonii.

 

Ninu atẹjade ti ọkunrin naa fi sita, lo tun ti ṣeleri iṣejọba rere, bi wọn ba le dibo yan oun gẹgẹ bi gomina ninu ibo to n bọ lọdun 2023.

 

Ọkunrin naa  tun lo akoko ọhun lati gba awọn Musulumi nimọran lati lo akoko awẹ naa yii gẹgẹ bi ọna lati fi mu idagbasoke ba ọrọ aje ati igbe aye irọrun fun mutumuwa.

 

Oludije Gomina ọhun  tun sọ pe ‘’Erongba wa nipinlẹ Ogun, ni lati jẹ ki eto ẹkọ di ọfẹ lati ileewe alakọọbẹrẹ titi de awọn ileewe giga, bẹẹ la si n gbero anfaani lati fawọn ọmọleewe ni oore-ọfẹ ati kawe ọfẹ ni oke-okun.

 

‘’Bakan naa ni idagbasoke yoo tun deba ilera wa lọna ti igbalode to fi jẹ pe ilera ọfẹ yoo maa wa fun ọmọde titi di ọmọ ọdun mọkanlelogun. Awọn oṣiṣẹ-fẹyinti naa yoo jẹ anfaani lati maa gba ẹtọ wọn deede nigba ti wọn ba wa laye.

 

O ni awọn tun ni lọkan lati taayọ awọn aṣeyọri Oloogbe Ọbafẹmi Awolọwọ, amọ nnkan to le jẹ kawọn ṣe awọn nnkan wọnyii ni bi awọn araalu ba le fi ibo wọn gbe ẹgbẹ oṣelu Action Aliance, wọle ninu ibo 2023, pẹlu ileri pe bi wọn ba foun ni atilẹyin, oun ko nii doju ti wọn.

 


No comments:

Post a Comment

Pages