Ẹ fi adura awẹ Ramadan ọdun yii mu atunṣe ba orileede yii- Bukọla Ṣaraki - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 1 May 2022

Ẹ fi adura awẹ Ramadan ọdun yii mu atunṣe ba orileede yii- Bukọla Ṣaraki

Abubakar Olubukọla Saraki, aarẹ ile igbimọ aṣofin tẹlẹ, ti rọ gbogbo awọn Musulumi lati lo awọn adura ti wọn gba lakooko awẹ Ramadan lati fi mu atunṣe rere ba orileede yii.

Ọkunrin yii sọrọ naa ninu atẹjade kan ti ọkunrin naa fọwọ si, ti akọwe iroyin ẹ, Yusuph Ọlaniyọnu, fi sita lo ti kọkọ bawọn ṣajọyọ ọdun itunnu awẹ ọdun yii pe o ṣoju ẹmi gbogbo wa.

O gba awọn ọmọ orileede yii nimọran lati fi adura wọn lakooko naa ran orileede yii lọwọ nitori ohun lo ṣi ṣe pataki bayii,o ni ohun lo si le gbe wa ro .

 

Aarẹ ile igbimọ aṣofin tẹlẹ, naa tun sọ pe opo pataki ti Ramadan duro le lori ni lati tọ ni sọna nigba igbe aye ọmọniyan lọna tootọ to si yẹ, ki a si tun maa fi dupẹ fawọn igbenija lori awọn ipenija ta a ba ti foju ri.

 

O sọ pe “Ni bayii ta a ti pari awẹ Ramadan, o yẹ ki a sa fawọn nnkan to le ko wahala ba ilera, orileede ati igbe aye wa, ki a si maa fojoojumọ ni ibẹru Ọlọrun lọkan ninu ohun gbogbo ti a ba n ṣe’’

 

 

Bakan naa ni  Bukọla Ṣaraki tun sọ fun wa pe a gbọdọ mu lara ẹkọ yii fi ifẹ han sawọn alabagbe wa, ki a jẹ ki alaafia ati jẹ wa logun ni gbogbo ọna.

 

O ni a gbọdọ ṣafihan eleyii pẹlu awọn ẹlẹsin yooku atawọn ẹya ti wọn ki i ṣe ti wa. O waa sọ pe idaniloju wa pe awọn Musulumi ti wọn ṣẹṣẹ pari awẹ wọn atawọn Kristẹẹni, ti wọn ti pari ti wọn ṣaaju lo akoko awẹ ọdun lati fi gbadura fun orileede yii, oun si nigbagbọ pe nipasẹ awọn adura yii, Ọlọrun yoo mu atunṣe rere ba orileede yii.

 

Ṣaraki waa pari ọrọ ẹ pe bi ibo ọdun 2023, ṣe n wọle wẹrẹ yii lati fi yan awọn adari tuntun, Oun gbadura itọsọna ati idari lati ọdọ Ọlọrun wa, lati le fi yan adari tuntun ti yoo mu ifọkanbalẹ ba gbogbo ọmọ orileede yii.

 


No comments:

Post a Comment

Pages