Àgbá òfífo ni Ládi Adébutú,kò ní ọpọlọ láti darí ìpínlẹ̀ Ògùn- Ṣẹgun Ṣowunmi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 28 April 2022

Àgbá òfífo ni Ládi Adébutú,kò ní ọpọlọ láti darí ìpínlẹ̀ Ògùn- Ṣẹgun Ṣowunmi

Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun, ti ṣapejuwe ẹni ti wọn jọ n dije fun tikẹẹti gomina, iyẹn Ladi Adebutu, gẹgẹ bi agba ofifo, ti ko ni nnkan to fẹẹ ṣe fun ipinlẹ Ogun ju pe ko tun da kun un lọ.

Ọkunrin naa sọrọ yii nibi apejẹ Iftaa, to ṣe pẹlu awọn oniroyin laipẹ yii, o sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ pe iru ọkunrun yii ni Baba ẹ, Oloye Kessington Adebutu, ṣatilẹyin fun lẹyin gba to lawọn ọmọ to ni ọpọlọ lori ju u lọ.

O sọ pe ki i sọrọ ibajẹ rara Ladi Adebutu ko ni ọgbọn bo ṣe le dari ipinlẹ, o ni bi wọn ba le fun iru wọn laaye, o dabi ẹni pe wọn tun fẹẹ fa ọwọ ogo ipinlẹ Ogun sẹyin ni, ni eyi tawọn ko si ni gba.

Oludije ọhun tun ṣalaye pe ‘’Ṣe ẹni ti ko le dari ileeṣẹ ẹ ni yoo  dari odindi ipinlẹ,mo roo lọkan mi pe Oloye Adebutu, to jẹ baba ẹ, ko ba ma ti ran an pe ko wa dije lati ṣe gomina. Wọn ni awọn ọmọkunrin mii in, eyi to bajẹ ju ninu wọn lo ni ko maa ṣakoso wa, ko le ri bẹ. Orukọ mi mni Ṣẹgun Ṣowunmi,  mo yatọ sawọn to n díbọ́n.

‘’Bi wọn ba fun un ni tikẹẹti, ọrẹ mi ni, ẹgbọn mi si ni pẹlu, mi o le ba a ja, nitori ọna to gba n ṣe oṣelu yatọ, mo ṣetan lati ni bii ọmọde’’ .

Bakan naa lo tun sọ  pe ti wọn ba dibo yan oun gẹgẹ bi gomina, ti wọn rii pe oun kowo ilu jẹ, ki wọn sọ oun si ẹwọn, nitori bi oun ba depo gbogbo awọn to ṣe owo baṣubaṣu loun yoo sọ sẹwọn.

O ni erongba oun lati di gomina ki i ṣe lati ṣowo ilu baṣubaṣu, tabi na owo naa lọna ti ko tọ, bikoṣe lati jẹ ki ọrọ aje ipinlẹ ọhun tun gberu si. Ki iyipada rere de ba awọn ọmọ ipinlẹ Ogun, kawọn si ma pawo wọle loorekoore.

Nitori ẹ lo ṣe sọ pe ẹni ti yoo ba jẹ igbakeji oun gbọdọ jẹ akinkanju lati ṣiṣẹ ki i ṣe aloku ẹnjini,nitori iṣẹ to wa niwaju ki i ṣe nnkan ti gomina le da ṣe.

Oludije Gomina ọhun tun ṣalaye siwaju pe ẹni to ṣẹṣẹ darapọ mọ ẹgbẹ to loun naa fẹẹ dije du gomina, iyẹn Jimi Lawal, awọn nnkan toun gbọ nipa tiẹ naa buru jọjọ, aimọye awọn eeyan lo ni wọn ni wọn ti ṣetan, bẹẹ loun tiẹ gbọ awọn oriṣi etekete ti wọn fẹẹ maa lo, amọ  ile ẹjọ ni yoo yanju ẹ nigbẹyin.

Otunba Ṣowunmi tun wa sọ pe bi ọrọ tikẹẹti yẹn ko ba wa bọ si, o ni awọn ọna mẹta toun naa ti la kalẹ, akọkọ ni pe oun yoo kọkọ wo bi igbesẹ naaa ba ṣe lọ, ti ko ba si tẹ oun lọrun oun yoo lọ ẹgbẹ oṣelu mii-in lati dije.

Ẹlẹẹkeji ni pe, toun ba rii pe ẹni ti wọn fun ni tikẹẹti ọhun ko ṣe gbẹmi le oun ṣetan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu alatako nitori pe oun ko fi oṣelu ipinlẹ Ogun ṣere. 

Ṣugbọn o sọ pẹlu idaniloju pe ọwọ oun ni tikẹẹti ọhun yoo bọ si.

 

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages