Ọba ti ipa rẹ ko ṣe e gbagbe ninu iran Yoruba ni Alaafin Ọyọ-OPC New-Era - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 26 April 2022

Ọba ti ipa rẹ ko ṣe e gbagbe ninu iran Yoruba ni Alaafin Ọyọ-OPC New-Era



Ẹgbẹ Oodua People Congress, New-Era, ti Oloye Rasak Arogundade Balogun, jẹ aarẹ wọn, ti ṣapejuwe ipapoda Alaafin tiluu Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi, kẹta,gẹgẹ bi adanu nla ninu iran Yoruba ati pe ipa rẹ ko ṣe e gbagbe laelae.

Ninu atejade kan ti  aarẹ ẹgbẹ ọhun fi sita, lorukọ igbimọ wọn, fun ti ipapada ọba to waja naa ni wọn ti sọ pe iku mu baba naa lọ lakooko tawọn iran Yoruba, si n kọ ninu ọgbọn ati oye wọn, ti wọn si tun ri ṣamulo nibẹ.

Wọn ni awọn ba gbogbo eeyan ipinlẹ Ọyọ paapaa awọn oloye Ọyọ lapapọ to fi mọ awọn ẹbi ọba Alaafin ilu Ọyọ kẹdun iku Baba Yeye naa,ti wọn ni wọn lọ fi abọ jẹ awọn baba nla wọn.

Ẹgbẹ OPC New-Era tun sọ pe ipa ti ko kere ni Ọba ọhun ko ninu igbelarugẹ aṣa, to si rii pe wọn ko jẹ ko di iparun ni akoko tiẹ.

Wọn bo tilẹ jẹ pe airotẹlẹ ni iku ọhun de wẹrẹ to si mu Alaafin lọ amọ ko si nnkan tawọn le ṣe ju pe kawọn tun dupẹ fun igbe aye ti wọn gbe, tawọn ọba ilẹ yooku si fi wọn ṣe awokọṣe

Wọn wa gbadura pe ki Olodumare tun pese iru ọba rere bayii fun ilu Ọyọ.

 


No comments:

Post a Comment

Pages