Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi ṣedaro Alaafin Ọyọ to waja - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 24 April 2022

Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi ṣedaro Alaafin Ọyọ to waja


 

Beeyan ba gbọ awọn ọrọ iṣiti ti Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, kọ lati fi ṣedaro Allafin tiluu Ọyọ,Ọba Lamidi Adeyẹmi kẹta, to waja, yoo mọ pe adanu nla niku ọba alaye naa jẹ fun iran Yoruba ati orileede yii lapapọ.

Ninu atẹjade ti oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun, fi sita lo ti sọ pe iku to pa ọba alaye ọhun, gba nnkan gidi lọwọ iran Yoruba.

 Ọkunrin ọhun sọ pe bi Alaafin ṣe faye silẹ to lọọ ba awọn irunmọlẹ atawọn baba nla ẹ yii ọfọ nla lo jẹ, bo tilẹ jẹ pe inu awọn to lọọ ba yii yoo maa dun pe ọmọ wọn ti wa fabọ jẹ wọn.

Ati pe iku to jẹ ọmọ iku, ti fopin si i ọdun mejilelaaadọta to lo lori itẹ niluu Ọyọ, o lo ti wa di ohun itan Ọba Lamidi Adeyẹmi naa ti jọba nigba kan ri.

O wa ṣapejuwe Ọba Alaafin Ọyọ, gẹgẹ bi ẹni to kun fun oye pẹlu ọpọlọ pipe, onifaaji atata, o duro tepọn pẹlu alaafia ara, abẹṣẹẹ-kuu-bii-ojo, ati ọba to mọ ọn jo bíi òkòtó, to tun jẹ akewi ọla lede Yoruba.

Ṣẹgun Ṣowumi tun sọ pe “Ta ni yóò sọ ijinlẹ Yoruba tẹ ẹ maa n sọ si wa mọ, ta lo tun ṣẹku ti yoo tumọ ohun ti aayan n filu wi, Alaafin to n bojuto awọn ohun ajogunba wa ti doriṣa o.

“Ọlayiwọla ọmọ Iku, omọ arun, Iku Baba Yeye, wogiri-lagiri ọmọ ojo pa ṣẹkẹrẹ mọlẹ. Sanbẹ sun, fapo rọri, Layiwọla hurun lojugun, penlebe hurun latẹlẹsẹ. Baba tiyin lo wo Fulani ti n lọ lọjọsi, to ni ta ni ẹrukẹru n fojudi, ta ni karambani fi ara ẹ pe. O gbona bii ẹlẹgun-un Ṣanpọnna, Ṣanpọnnna o gbona ẹlẹgun rẹ lo gbona.

Ọtunba tun ni “Haa, iku si yọwọ ẹni nla bíi eyi lawo! Alọ rẹ yoo dáa, Adeyẹmi, awọn irunmọlẹ yoo f’ayọ ki ọ kaabọ nilana tode ọrun. Inu Ladigbolu yoo dun, Ọba Adeyẹmi akọkọ yoo dunnu pe o de, Ofiran Baba Ọranyan ko ni ṣai ki ọ kaabọ tayọtayọ, Elenpe, Aolẹ atawọn mi-in ti wọn ti lọ ṣaaju rẹ yoo ṣoro awo Oriṣa fun ọ.

“Ilẹ Yoruba mọ pe o gbiyanju, gbogbo ọmọ ilẹ Yoruba lọkunrin at’obinrin ni wọn n ṣedaro rẹ ti wọn si n fẹ kí Ọlọrun Allah to ṣẹda rẹ ṣaanu fun ọ, ko pa awọn aṣiṣe rẹ rẹ”

Ile iwosan Afẹ Babalọla,  niluu Ado-Ekiti,  ni Ọba Lamidi Adeyẹmi, ti jade laye laarọ Satide, to kọja yii, ti wọn ko si jẹ ki oku ẹ pẹ, nilẹ ti wọn fi bẹrẹ eto isinku ẹ nilana musulumi ati abalaye.

Bakan naa ni wọn ti bẹrẹ oro atawọn eto iṣẹmbaye ti wọn ma ṣe lẹyin isinku ọba. Ọba Lamidi Adeyẹmi, ibi to ba wa ilẹ ire oooo.

 


No comments:

Post a Comment

Pages