Oludije gomina fẹgbẹ oṣelu Action Alliance, AA, nipinlẹ Ogun, Dokita Samuel Olufẹmi Adeyẹmi, ti fi awọn eeyan ipinlẹ naa lọkanbalẹ pe gbogbo agbara loun yoo sa lati mu ayipada rere ba wọn, bi oun ba wọle ninu ibo to n bọ lọdun 2023.
Ọkunrin yii sọrọ naa lakooko to n ki awọn eeyan ipinlẹ ọhun ku ayẹyẹ ọdun ajinde, ta a wa ninu ẹ bayii.O sọ pe, gẹgẹ bi gbogbo wa ṣe mọ pe, Jesu Kristi, fi ara da itiju, to si ku fun wa lori igi agbelebu, nitori ki awa le ni igbala, to si mu ireti wa fun wa. O ni idi niyi ta a fi n ṣeranti ẹ lọdọọdun, nitori oun ni olugbala wa.
O fikun ọrọ ẹ pe ki i ṣe tuntun mọ ẹgbẹ oṣelu APC, ti ba ọpọ nnkan jẹ fawọn araalu, ti wọn si fojoojumọ ko awọn eeyan sinu irora.
Ṣugbọn, o ni bi ogo ti n jẹ ti Ọlọrun, tawọn eeyan ipinlẹ Ogun, ba le fi ibo wọn gbe oun wọle, oun ṣetan lati mu ayipada rere wa, Oun si ṣetan lati fun wọn ni ireti eyi ti yoo ran ọjọ iwaju wọn lọwọ.
O wa rọ awọn eeyan lati ri pe kaadi ibo wọn wa lọwọ wọn, nitori oun lo ṣe pataki lati fi le ẹgbẹ APC, jade kuro nijọba nipinlẹ naa. O tun wa gba a ladura pe ọdun ayọ lọdun ta a n ṣe yii yoo jẹ fun gbogbo mutumuwa.
No comments:
Post a Comment