APC Ewekoro dide atilẹyin fun Ọnarebu Adijat fun ipo aṣoju-ṣofin l'Abuja - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 16 April 2022

APC Ewekoro dide atilẹyin fun Ọnarebu Adijat fun ipo aṣoju-ṣofin l'Abuja


 

Ẹsẹ o gbero,lọjọ Furaidee, ana, nigba tawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, tijọba ibilẹ Ewekoro, gba alejo Ọnarebu Adijat Ọladapọ-Adelẹyẹ, to fẹẹ jade dupo aṣoju-ṣofin, fun agbegbe Ifọ/Ewekoro, ninu ibo to n bọ lọdun 2023.

 

Ibi ipade ọhun la gbọ pe o ti fikunlukun pẹlu awọn oloye wọọdu ati tijọba iblẹ naa, lati mọ jẹ ki wọn mọ erongba ẹ ati awọn eto to nii fun wọn, ti wọn ba fun ni tikẹẹti lorukọ ẹgbẹ naa, Ko tiẹ to de lawọn eeyan ti wa lori ijoko ti wọn si fẹẹ gbọ ohun ayọ to ni fun wọn ọhun.

 

Gẹgẹ ni ẹ ṣe mọ, ninu ka fi ọgbọn ṣagbekalẹ ọrọ lọna ti yoo ye eeyan, Ọnarebu Adijat, ko ṣe e fọwọ rọ sẹyin, idi niyii to fi doju tawọn eeyan ẹ nigba to n bawọn sọrọ lati le mọ awọn nnkan to nii lọkan fun wọn

 

Lara awọn nnkan to sọ pe oun ni fun wọn ti wọn ba le foun ni tikẹẹti aṣoju-ṣofin agbegbe naa niluu Abuja, ni ṣiṣe onigbọwọ fawọn aba ti yoo mu idẹrun bawọn, eto ironilagbara gidi ti tako tọrọ kọbọ ti ko ni itumọ. Awọn iṣẹ akanṣe lawọn agbegbe to yi Ifọ, Ewekoro ka.

Awọn yooku tun ni lati farajin nipa riran ọmọ ẹgbẹ lọwọ, Jijẹ anfaani to dara fawọn eeyan Ewekoro, ati ṣi ṣe awọn eto imayedẹrun lati fi ro awọn ọdọ, obinrin ati arugbo lagbara.

 A fi ki oludije naa maa kuro nibi to ti n sọrọ, bi awọn agbekalẹ ọrọ ẹ ṣe dun mọ wọn leti.

 

Ọnarebu Adijat waa lo akoko naa lati tun fi tan imọlẹ lori ipo to fẹẹ jade fun naa, o ni Ifọ ti ṣee ni ẹẹmẹta nigba tawọn Ewekoro yoo pari saa kẹta ti wọn naa nigba ti Ọnarebu Ibrahim Ayọkunle Isiaka, to wa nibẹ bayii ba pari saa keji ẹ.

 

Lẹyin to pari ọrọ ẹ, lawọn ibeere ọlọkan-ọ-jọkan waye ti akọni obinrin naa si da wọn lohun pẹlu igboya. Ti wọn si ṣeleri fun un pe awọn yoo ṣe atilẹyin nla fun lati gba tikẹẹti naa, ti yoo si wọle.

 


No comments:

Post a Comment

Pages