Ọna lati fopin si ijakulẹ eto aabo lawọn ẹyin odi ilu jẹ mi logun- Ṣẹgun Ṣowumi - BO SE RI

Breaking

Saturday 16 April 2022

Ọna lati fopin si ijakulẹ eto aabo lawọn ẹyin odi ilu jẹ mi logun- Ṣẹgun Ṣowumi


Ọgbẹni Ṣẹgun Ṣowunmi, oludije ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣeluPeople’s Democratic Party (PDP), ti sọ pe ọkan pataki to jẹ oun logun ju ti wọn ba le dipo yan oun gẹgẹ bii gomina nipinlẹ Ogun, ni lati wa atunṣe si ijakulẹ eto aabo to bawọn finra lawọn ẹyin odi ilu.

Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to ṣabẹwo lọ sọdọ Alaye tiluu Ayetoro, nijọba ibilẹ Yewa North, nipinlẹ Ogun, nibi ipade to lọọ ṣe pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa.

O sọ pe inu oun ko dun si bi eto aabo ṣe n lọ lagbegbe Yewa North, o akoko ti waa to ti wọn ba dibo yan oun lati le jẹ ki ipenija ti wọn koju di oun afisẹyin.

Gẹgẹ bo ṣe wi, fifi orukọ awọn eeyan silẹ yoo jẹ ki ijọba atawọn eleto aabo mọ awọn agbegbe ibi ti wọn ba wa lakooko ti wahala ba fẹ waye.

Bẹẹ lo tun rọ awọn olori agbegbe lati ri i pe wọn fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lati maa ta wọn lolobo. O ni ohun kan tawọn ri to jẹ awọn eeyan naa logun ni aabo ti wọn koju lori awọn darandaran, awọn apanijaye atawọn mii-in.

Oludije naa sọ pe oun mu dawọn loju pe ko sẹni ti wọn yoo le kuro kaka bẹẹ bi aabo yoo ṣe daju lori wọn. O wa rọ awọn Baalẹ lawọn agbegbe tọrọ naa kan lati gba wọn lamọran ọna ti wọn le gba ran wọn lọwọ lori ọrọ yii

O ni inu oun dun pe awọn eeyan ti mu da oun loju paapaa julọ awọn ọmọ ẹgbẹ PDP,  bẹẹ lo tun fi idunnu ẹ han si Alaye tiluu Ayetoro atawọn aṣoju wọn lati agbegbe Yewa North ati Imẹkọ Afọn.


No comments:

Post a Comment

Pages