Lati le jẹ ki idibo to n bọ nipinlẹ Ekiti ati Ọṣun lọ nirọwọ-rọsẹ, ẹgbẹ to n ṣagbega ilẹ Yoruba, iyẹnYoruba Appraisal Forum (YAF), ti bẹrẹ ilanilọyẹ fawọn eeyan ipinlẹ ọhun.
Lọjọ Aje, Mọnde, ati Tusidee, tii ṣe iṣẹgun ọsẹ yii lawọn eeyan ọhun balẹ sawọn ipinlẹ mejeeji ọhun lati bawọn eeyan sọrọ lori bi ibo gomina ti yoo waye lawọn ipinlẹ mejeeji naa yoo ṣe lọ laini wahala tabi itajẹsilẹ.
Ẹgbẹ YAF, ti wọn ti n lọọ kaakiri awọn ilẹ Yoruba, ni wọn polongo ti wọn si tun kede lati tu aṣiiri awọn eeyan kọn ti wọn fẹẹ fi ibo to n bọ lọna yii da wahala silẹ. Lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹfa,ọdun yii ni ibo gomina tipinlẹ Ekiti yoo waye nigba tipinlẹ Ọṣun, yoo waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keje, ọdun yii.
Ẹgbẹ to n ṣagbega ilẹ Yoruba ti wọn gbe awọn kaadi da ni pẹlu akọle oriṣiriṣi ni ede abinibi ati Yoruba, ni wọn fi n rọ awọn eeyan ki wọn jẹ ki ibo to n bọ naa ṣe eṣo rere. Bẹẹ ni wọn tun gba jọba,awọn eleto aabo nimọran lati ma ṣe gba awọn ti wọn fẹẹ ṣonigbọwọ fawọn adaluru, nitori ki ibo ma ba a waye laaye.
Adeṣina Animashaun to jẹ alaga ẹgbẹ naa lapapọ, to ṣaaju awọn eeyan ọhun, sọ pe erongba awọn ti wọn ko fẹẹ jẹ ki ibo naa waye ni lati da wahala, ki wọn si ba ilẹ Yoruba jẹ.
O sọ di mimọ pe ẹgbẹ naa ko ni ṣatilẹyin fun ẹnikẹni tabi ẹgbẹkẹgbẹ ti wọn ba ṣe onigbọwọ fawọn to ba fẹẹ da wahala silẹ nilẹ Yoruba ati lorileede yii. Bẹẹ lo ni awọn ko ni bawọn lọwọ si ẹnikẹni tawọn ọba ilẹ Yoruba ko ba fọwọ si..
O ni ki ilu toro, ki alaafia si jọba lawọn wa ati pe ojoojumọ lawọn yoo maa wa ọna, tilẹ Yoruba yoo fi toro.
No comments:
Post a Comment