Oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu Action Alliance,AA, Dokita Samuel Olufẹmi Adeyẹmi, ti sọ pe bi ogo ti n jẹ ti Ọlọrun, oun Gomina to wa nipo bayii, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, yoo gbejọba lee lọwọ gẹgẹ bi Gomina tuntun lọdun 2023.
Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n bawọn oniroyin sọrọ, o sọ pẹlu idaniloju awọn araalu ti ṣetan lati kuro ninu ajaga tẹgbẹ oṣelu APC, ko wọn si nipinlẹ Ogun, ti wọn si fẹẹ wa ọna abayọ.
O sọ pe gbogbo awọn ilana marun-un ti Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ ti la kalẹ lawọn yoo tẹle ṣugbọn awọn yoo tun fi ti wọn kun, eyi ti yoo fi tayọ, tawọn araalu yoo fi mọ pe awa lati wa farajin fun wọn ni.
O ni tiwọn yoo daa lori awọn iwadii igbalode ti yoo pese iṣẹ fawọn araalu ti yoo si jẹ ki wọn maa gbe igbe aye irọrun. O ni oun ko ṣetan lati tu gbogbo awọn nnkan tawọn ni lọkan sita bayii, nitori kawọn kan tun ma lọọ ji lo.
Amọ o n i ilera ọfẹ ṣe pataki foun, nitori oun naa janfaani nipa ilera ọfẹ naa, o ni ka ni ti ki i ba ṣe ipasẹ ẹ ni, oun ko baa ti ku. Nitori idi eyii loun ṣe pinnu lọkan oun pe toun ba depo naa, o di dandan koun ṣagbekalẹ ẹ.
Oludije gomina fẹgbẹ oṣelu AA, tun waa fikun ọrọ ẹ pe tun sọ pe itiju nla lo jẹ nilẹ Yoruba, pe titi di akoko yii, Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ, ni wọn maa fi n ṣe odiwọn, pe wọn ko tii ri eyi to tayọ.
Idi niyii to fi ni oun pinnu lati ṣe awọn nnkan to tayọ nipa agba oṣelu naa, nipa ifarajin ati ifẹ ọmọniyan bẹẹ ki oun gbogbo ko si maa lọ, bo ṣe yẹ ko lọ.
Dokita Adeyẹmi to tun jẹ oniṣiro owo ati agbẹjọro tun fi kun ọrọ ẹ pe awọn iriri toun ti ri lawọn iṣẹ toun yan an laayo loun yoo lo lati ri pe irọrun deba awọn araalu.
Bẹẹ lo tun sọ pe awọn yoo tun rii pe iṣẹ ati iya dopin fawọn eeyan paapaa awọn arugbo, nitori awọn yoo ṣeto kan nibi ti wọn yoo ti gba tikẹẹti ti wọn yoo fi maa fun wọn lounjẹ loṣooṣu.
O waa fakoko ọhun gba awọn araalu nimọran pe pataki ni kaadi idibo, ki wọn ri pe wọn lọ forukọ silẹ lati gba kaadi ọhun, nitori ẹtọ wọn ni gẹgẹ bi ọmọ orileede rere.
No comments:
Post a Comment