Gbajumọ sọrọsọrọ, Jabulani, fẹẹ gbe kasẹẹti orin ‘’Spcial Grace’ jade - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 9 April 2022

Gbajumọ sọrọsọrọ, Jabulani, fẹẹ gbe kasẹẹti orin ‘’Spcial Grace’ jade



 

Gbogbo eto lo ti pari fun gbigbe kasẹẹti orin tuntun kan jade, ti akọle ẹ n jẹ Special Grace, gbajumọ sọrọsọrọ nni Jọlaoluwa Afọlabi, tọpọ mọ si Jabulani, ni yoo gbe jade.

 

Gẹgẹ bi atẹjade to tẹ wa lọwọ, wọn orin tuntun yii ti ẹni to tun jẹ olukọ, ajafẹtọọ, to ti ran ọpọ eeyan lọwọ ninu igbesi aye wọn ni apa kan ninu ẹ jẹ Ọmọ Àsé.

 

A gbọ pe laipẹ yii ni kasẹẹti ti ata to, ti iyọ si dun ọhun yoo jade si ori atẹ. Orin Special Grace, ni wọn lo tun kun fun imisi ni wọn ni Jabulani fi gbe Ọlọrun ga ati pẹlu pe labẹ bo ti wu ki o ri a gbọdọ maa ni igbẹkele ninu ẹ.

 

Nigba to n sọrọ, ọkunrin to ti lo ogun ọdun nidii iṣẹ sọrọsọrọ sọ pe  aṣiwere eeyan nikan lo le ṣafojudi oore Ọlọrun ninu aye awa ẹda.

 

O ni Special Grace yii wa fun imọriri oore Ọlọrun, to si kumn fun ọpọ imisi, eyi tọpọ awọn eeyan gbọdọ ni nile, ki wọn si maa gbọ. Pẹlu adura pe oore ọfẹ Ọlọrun ko nii fi gbogbo wa silẹ.

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages