Dẹjọ Tunfulu ti dara ilẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 1 April 2022

Dẹjọ Tunfulu ti dara ilẹ


Ni nnkan bi aago mẹrin irọlẹ yii ni wọn sin ọkan lara awọn alawada onitiata nni Kunle Makinde Tokunbọ, tọpọ awọn eeyan mọ si Dẹjọ Tunfulu, sile ẹ to wa ni Agbọwa, Ikorodu, nipinlẹ Eko.

 Latigba ti ariwo iku oṣere ọhun ti gbode lawọn eeyan paapaa julọ awọn onitiata fi n rọ lọ sile ẹ lati la bawọn kẹdun, koda awọn kan ko tete gbagbọ nitori gẹgẹ bi ọjọ onii ṣe jẹ April fuulu, ti wọn si ro pe wọn tan awọn eeyan jẹ ni.

Ṣugbọn nigba ti wsọn ri aworan oku ọkunrin yii kaakiri ori ẹrọ ayelujara, ni wọn to gbagbe loootọ ni oṣere naa ti dagbere faye, ibeere ti wọn si tun n beere lọwọ ara wọn ni pe iru iku wo lo pa a gan-an.

Ohun tawọn kan sọ pe aisan ti wa lara Dẹjọ Tunfulu tẹlẹtẹlẹ, to fi jẹ pe awọn to ri n beeere lọwọ ẹ pe ki lo n ṣẹlẹ sii, wọn ni ohun to ṣaaba jẹ ki kinni ọhun tun tete gba ẹmi ẹ ni pe ko funra ẹ ni itọju to peye.

Wọn bi aisan yii ṣe n wọ lara to o oju bintin lo fi n wo, ko to waa di pe iyẹn gba ẹmi ẹ laaarọ yii. Sibẹ naa kayeefi lo si n jẹ pe oṣere tiata yii naa ti dara ilẹ.

Ọpọ awọn oṣere to ba wa sọrọ ni wọn sọ pe Dẹjọ jẹ eeyan gidi to ni akikanju, ti ki i fisẹ ẹ ṣere, to si kundun lati maa ran awọn ti wọn jọ jẹ oṣere lọwọ.

Adura ti wọn si n gba fun un lẹyin ti wọn sin in tan ni pe ki Ọlọrun fi ọrun kẹ, ko pa gbogbo aiṣedeede ẹ rẹ ẹ

 


No comments:

Post a Comment

Pages