Alfa Musibau Ganiyu di Imọlẹ Adinni Imọsan - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 27 March 2022

Alfa Musibau Ganiyu di Imọlẹ Adinni Imọsan


Musibau Ganiyu di Imọlẹ Adinni Imọsan

Lana-an, ọjọ Abamẹta, Satide, ni ẹgbẹ musulumi kan ti wọn pe ni Imọsan Musilim Community fi oye ẹsin da ọkan lara awọn gbajugbaja olori ẹlẹsin nni Alfa Musibau Adekunle Ganiyu lọla.

Nibi ayẹyẹ eto naa to waye niluu Ijẹbu Imọsan, lawọn eeyan jakanjakan ti peju pesẹ lati yẹ ọkunrin naa si. Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, wọn lawọn ipa pataki ti ọkunrin naa ti ko ninu ẹsin paapaa julọ ninu ilu naa lo mu kawọn ẹgbẹ musulumi ọhun fi we lawani oye le ọhun naa lori.

Nigba ti Imọlẹ Adinni fun ilu Imọsan tuntun naa sọrọ, o dupẹ lọwọ awọn ti wọn we lawani oye tuntun ọhun le oun lori, o ni eyi yoo tun jẹ ki oun tẹsiwa ju ninu igbelarugbẹ ẹsin musulumi ọhun.

O tun fikun pe niwọngba toun ba si fi wa nile aye yii oun ko nii jẹ ko rẹ oun lati ma wa igbega fun ẹsin Islam yii. 


No comments:

Post a Comment

Pages