Tommy olori ọmọ ẹgbẹ okunkun tawọn alatako wọn pa da wahala silẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 25 March 2022

Tommy olori ọmọ ẹgbẹ okunkun tawọn alatako wọn pa da wahala silẹ


 

 

Titi di akoko ta a wa yii, inu fu, aya fu, lawọn eeyan agbegbe Oluwo niluu Abẹokutam nitori bawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ṣe gbena woju ara wọn, ti wọn si pa ọkan lara awọn ọga wọn, ti wọn pe orukọ ẹ ni Tommy.

 

 

Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, ti sọ pe awọn mejidinlogun, lọwọ ti tẹ lori wahala to waye lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee,  mọjumọ ọjọ keji, tii ṣe ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja sibẹ ọpọ awọn ọmọleewe to n gbe laduugbo ọhun ni wọn ti sa kuro, ti wọn ko si mọ nnkan to le waye.

 

Gẹgẹ bi iwadii wa, nibi ija to waye ọhun ni wọn ti Tommy lagbegbe Panṣẹkẹ,ti wọn ko si mọ awọn to pa a titi di akoko yii ṣugbọn wọn ni ko le ṣe lẹyin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun.

 

Ṣe ni a gbọ pe wọn sa ọkunrin naa yannayanna titi ti ẹmi fi bọ lara ẹ, ti wọn si fi i silẹ ninu agbara ẹjẹ. Ohun ti wọn lawọn kan n sọ ni pe awọn ọmọ Aiye lo ṣiṣẹ ọhun, nitori wọn ni ọmọ Ẹyẹ ni ọga ti wọn pa naa.

 

Nibi tọrọ naa le de ibẹrubojo ko jẹ kawọn to ni ṣọọbu lagbegbe naa ta ọja wọn lọjọ keji, nitori wọn lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa n lọ, ti wọn si n bọ lati fi gbẹsan.

 

Ariwo ti wọn lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa n pa ni pe awọn ko le gba ki iku ọga wọn ti wọn pa lọ lasan, awọn ni lati gbẹsan ni, bẹẹ ni wọn gbe ọkada lọ, ti wọn gbe bọ lọjọ naa.

 

Ṣugbọn awọn ọlọpaa ti sọ pe mejidinlogun ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun lọwọ ti tẹ, ti wọn si n ṣe iwadii lẹnu wọn nipa nnkan ti wọn mọ nipa Tommy, ti wọn da ẹmi ẹ legbodo.

 

Wọn wa ni kawọn ara adugbo ọhun fọkanbalẹ nitori awọn ṣetan lati pese aabo to jọju fun wọn.


No comments:

Post a Comment

Pages