Fọọmu oludije Gomina ti Sẹgun Ṣowunmi gba tun ti sẹrubawọn - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 25 March 2022

Fọọmu oludije Gomina ti Sẹgun Ṣowunmi gba tun ti sẹrubawọn


 

Lọsẹ to kọja ti Ọgbẹni Ṣẹgun Ṣowunmi, to jẹ agbẹnusọ fun olupolongo Atiku Abubakar, lori ibi aarẹ fọdun 2019, jade sita pe oun ṣetan lati dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun, yẹyẹ lawọn kan n ṣe, ti wọn sọ pe ariwo lasan ni ati pe nibo ni yoo ti rowo nla ti yoo fi gba fọọmu ọhun.

 

Ṣugbọn ni bayii,ọkunrin naa ti doju tawọn ọta ẹ, to si jẹ ki wọn mọ pe loootọ ni oun pinnu lati dije fun ipo gomina ọhun.  Ṣẹgun Ṣowunmi atawọn eeyan ẹ ninu ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ogun, ni wọn gunlẹ si oluuleṣẹ ẹgbẹ wọn to wọ niluu Abuja iyẹn Wadata House, to si gba fọọmu ọhun.

 

Bo tilẹ jẹ pe titi di akoko yii lawọn eeyan ko gbagbọ pe ọkunrin naa ti gba fọọmu oludije, ti wọn si n beeere pe awọn fẹẹ ri fọto ọhun, Idi niyii ta a fi gbe e sita ;ati jẹ ki wọn mọ pe ọrọ naa ki i ṣe ere rara.

Ohun to wa jẹ kayeefi ninu ọrọ naa ni pe latigba tiọkunrin ọhun ti jade, ti wọn si ti gbọ pe o ti gba fọọmu ni ara ko ti ro okun, ti ko si rọ adirẹ paapaa julọ awọn to wa lọdọ Ladi Adebutu.

 

Idi abajọ ni pe nnkan ti wọn ko ro ni wọn wa n ba bayii, ero wọn ni pe ko nii si ẹlomii-in ti yoo tun jade dupo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun, lẹyin Adebutu.

 

Nitori bi wọn ṣe sọ pe oun gbọ lo n gbọ bukata ẹgbẹ naa latigba toun ati Oloogbe Buruji Kashamu ti jọ n faa,ti wọn si lawọn kan ti n fi lọkanbalẹ pe ko sewu mọ, ati pe ko le ni atako kankan rara fun ibo 2023, laimọ pe oṣelu ko gba bẹẹ.

 

Iwadii tiẹ fi ye wa pe ọrọ naa ti n di ibinu si awọn kan lara ti ẹru si n ba wọn pẹlu nitori wọn ni wọn ko mọ ayo ti Ṣẹgun Ṣowunmi fẹẹ gba wọn, amọ sa, awọn kan ti wọn lẹnu ninu ẹgbẹ naa sọ pe ti ọkunrin agbẹnusọ fun Abubakar Atiku lawọn yoo ṣe, nitori awọn mọ pe gbogbo nnkan ti eeyan fi n ṣe gomina lo ni.

Lọrọ kan Ṣẹgun Ṣowunmi ti n ṣẹru ba awọn kan ni PDP, o si ti n ko idaamu bawọn

 


No comments:

Post a Comment

Pages