Mo ṣetan lati mu ayipada rere ba orileede yii ti mo ba di aarẹ- Oludije NNPP - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 23 March 2022

Mo ṣetan lati mu ayipada rere ba orileede yii ti mo ba di aarẹ- Oludije NNPP

Oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu New Nigerian People Party, NNPP, Joseph Oluwadamilare Faduri,  ti sọ pẹlu idaniloju gbogbo agbara oun loun yoo sa lati mu ayipada ba orileede yii ti wọn ba le dibo yan oun gẹgẹ bi aarẹ orileede ninu ibo to n bọ lọdun 2023.

Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n ba awọn fọrọjomitoro ọrọ nigba to ṣabẹwo wa sọdọ awọn ọmọ ẹgbẹ wọn to wa nipinlẹ Ogun, fun atilẹyin wọn koun le ba depo ọhun.

O sọ pe gbogbo awọn ọmọ orileede yii lo ti foju winna awọn iṣoro tawọn to wa nijọba to wa lode yii ti mu ba wọn, idi niyii ti wọn fi gbọdọ lo ibo wọn lati fi le wọn kuro, ki wọn si dipo foun labẹ ẹgbẹ oṣelu NNPP, lati le mu idunnu bawọn.

Bakan naa lo fikun ọrọ ẹ pe akoko ti to fun awọn ọdọ lati di aarẹ orileede yii, nitori eyi tawọn arugbo dari wa to ti to gẹ, o ni o si kun lara nnkan to mu ifasẹyin ba wa, idi si niyii tawọn ọdọ naa fi n ji pepe lati rii pe wọn gba akoso.

O ni idaniloju wa pe tawọn ọdọ ba fi le depo aarẹ paapaa julọ, ko ni si nnkan to n jẹ ijakulẹ, nitori pe ọpọlọ  wọn si ji pepe lati dari ilu, wọn yoo si maa ṣe awọn nnkan to tọ, to si yẹ lakooko.

Lori ọrọ ti Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, toun naa jẹ oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, sọ nipa kan pe kawọn ọdọ si nii suuru di ọdun mẹjọ toun ba fi ṣe aarẹ, ki wọn to jade dupo, ọkunrin naa sọ pe nnkan to ba wu onikaluku lo le sọ gẹgẹ bi erongba tiẹ, ṣugbọn loju toun akoko ọdọ ti to, wọn si ti gbaradi lati ṣiṣẹ.

Faduri sọ pe “Gẹgẹ bi ọmọ Naijiria, gbogbo nnkan teeyan n ni lati di aarẹ ni mo ni,ọdọ ni mi, ọmọ Naijria ni mi pẹlu, bi a ba si n sọrọ nipa aṣaaju, a ni lati sọ nipa awọn eeyan ilu,, mo lawọn eeyan gidi ninu ẹgbẹ mi NNPP,ti wọn si dara si mi’’

‘’Mo tun fẹẹ ki ẹ mọ pe awọn ara orileede yii ni wọn yoo sọ nipa ibo ki i ṣe Tinubu tabi Atiku, lakooko yii o da mi loju pe oju yoo ti wọn pẹlu owo wọn, wọn ti dagba ninu oṣelu, o yẹ ki wọn fi silẹ fawa ọdọ. Sebi wa ni wọn n lo tẹlẹ lati fi yi ibo amọ ni bayii ko si nnkan to jọ bẹẹ mọ.’’

O waa pari ọrọ ẹ pe Ọlọrun yoo lo oun bo ṣe lo Josefu ninu bibeli lati gba awọn eeyan ẹ la, toun yoo si gba awọn ọmọ orileede yii la.

 


No comments:

Post a Comment

Pages