PDP, IPAC ni Ṣẹgun Ṣowunmi lawọn fẹẹ ko dije fun ipo Gomina l’Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 17 March 2022

PDP, IPAC ni Ṣẹgun Ṣowunmi lawọn fẹẹ ko dije fun ipo Gomina l’Ogun


Ẹgbẹ oṣelu PDP ati apapọ ẹgbẹ oṣelu nipinlẹ Ogun, ta a mọ si IPAC, ti sọ pe ki agbẹnusọ olupolongo fun Abubakar Atiku, Ọgbẹni Ṣẹgun Ṣowunmi, jade dupo gẹgẹ ni gomina nini ibo to n bọ lọdun 2023.

Nibi ipade ita gbangba kan to waye ni Panṣẹkẹ, niluu Abẹokuta, ni gbogbo wọn ti fẹnuko pe ọkunrin naa kaju ẹ lati di gomina nipinlẹ Ogun, nitori ọlọpọlọ pipe ni.

Wọn ni gbogbo nnkan ti eeyan ni lati fi tukọ ipinlẹ naa ni Ṣẹgun Ṣowumi ni, tawọn si mọ pe o le doju tawọn to ba depo naa, bẹẹ ni wọn tun ṣeleri fun un gbogbo atilẹyin to ba yẹ lawọn yoo ṣe fun ọkunrin naa ti akoko ba to.

Ninu ọrọ ti Ṣẹgun Ṣowunmi lo ti dupẹ lọwọ awọn ẹgbẹ oṣelu naa lori bi wọn ṣe ro rere ro oun. O sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ foun pe ija to n waye ninu ẹgbẹ PDP, ni ko jẹ i wọn ti pada sinu ogo ti wọn wa tẹlẹ nipinlẹ naa.

O sọ pe bi awọn ba le fi imọ sọkan tawọn si gbagbe gbogbo rogbodiyan to ti waye sẹyin, o da oun loju pe ẹgbẹ naa ni yoo jawe olubori ninu ibo to n bọ lọdun 2023.

O ni gbogbo erongba wọn lati bi ọdun meloo lati yanju gbogbo wahala to n waye yii ko so eso rere, nitori aifẹ gba fẹnikan. O wa sọ pe bi wọn ṣe ni ki oun jade lati dupo gomina,oun ṣetan lati jade, koun si ṣe nnkan ti wọn n fẹ. O waa bẹbẹ fun ifọwọsowọpọ lati le jẹ ki erogba gbogbo wọn di mimuṣẹ.

Ninu ọrọ Samson Ogunsanya, to jẹ alaga fẹgbẹ awọn apapọ oṣelu nipinlẹ Ogun, to ṣaaju awọn yooku ẹ wa, o sọ pe awọn wa lati fi atilẹyin wọn han si Ṣẹgun Ṣowunmi, lati jade dupo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP.

Lara awọn to tun wa nibe ni Arabmbi ati Moshood Adeṣina tawọn naa wa ninu ẹgbẹ IPAC. Lọrọ kan, ariwo Ṣẹgun Ṣowunmi, ni PDP, n pa bayii lati wa dije fun ipo gomina.  

 

 

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages