Titi di akoko ta a n kọ iroyin yii lọwọ lawọn ẹbi Sulaimon Balogun, to jẹ akẹkọọ jade nileewe giga yunifasiti Ọlabisi Ọnabanjọ, Agọ n waye n wa ọkunrin naa, ti wọn si sọ pe yala aye tabi oku ẹ, awọn fẹẹ ri nnkan awọn.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, nigba ti Sulaimon to kọ nipa Kẹmika sayẹnsi, nileewe ọhun jade tan lo mu iṣẹ ayaworan laayo.
Wọn ni iṣẹ yii naa lo gba ni Kano, nibi ayẹyẹ kan, Alaba Rago, ni Eko, wọn lo ti wọ mọto sibi ayẹyẹ igbeyawo ọrẹ ẹ, iyẹn lọjọ keji, oṣu yii, ti wọn ni ko si debẹ.
Latigba naa la gbọ pe awọn ẹbi ẹ, to fi mọ awọn ọrẹ fi n wa, nigba ti foonu ẹ ko lọ. Nigba ti wọn lọ si Alaba Rago, nibi to ti wọ mọto, nnkan ti wọn sọ pe fun wọn ni pe mọto to wọ lọdọ wọn nijamba mọto, ti wọn si ti sin in.
Iyalẹnu ni wọn lo jẹ pe wọn ko gba aye lọwọ ẹbi ko to di pe wọn gbe igbesẹ ọhun.
Ọkan lara awọn ẹbi to ba wa sọrọ sọ pe awọn ti fọrọ naa to awọn ọlọpaa to wa lagbegbeFestac Area A leti, ti wọn si sọ pe ọrọ naa mu ifura dani.
Bẹẹ la tun gbọ pe wọn ti kọwe ẹhonu sawọn ọlọpaa lori iku to mu ifura dani ọhun. Wọn ni bawo ni agbalagba ṣe le ku ninu ijamba mọto, ti wọn yoo si sare sin in laisọ fun ẹbi ẹ kankan, koda ti awọn ti wọn le pe ti wọn sunmọ ọn wa ninu iwe to kọ ni garaaji naa, wọn ni nnkan kan gbọdọ ṣẹlẹ, awọn si ni lati mọ ọn.
Wọn wa rọ ijọba atawọn araalu lati bawọn ṣewadii, lati mọ ohun to ṣẹlẹ naa.
No comments:
Post a Comment