Awọn kan fẹẹ da wahala silẹ nilẹ Yoruba nitori ibo 2023- Ẹgbẹ YAF - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 16 March 2022

Awọn kan fẹẹ da wahala silẹ nilẹ Yoruba nitori ibo 2023- Ẹgbẹ YAF

 

Ajọ kan to n gbe ilẹ Yoruba ga, iyẹn Yoruba Appraisal Forum, YAF, ti ke gbajare sita pe awọn kan ti n gbimọ pọ lati da wahala silẹ nilẹ Yoruba atawọn agbegbe kan lorileede yii lati fi le gbegi dina ibo to n bọ lọdun 2023.

 

Adeṣina Animashaun, to jẹ alakoso ẹgbẹ ọhun lapapọ lo ke gbajare naa sita ninu atẹjade kan ti wọn fi sọwọ si wa. O sọ pe awọn mọdaru kan ti n sa ara wọn jọ kaakri orileeede yii lati bẹrẹ awuyewuye eyi to le mu ẹmi la silẹ atawọn iwa janduku mii in, lati ma ṣe jẹ ibo ọdun to n bọ naa waye.

 

Gẹgẹ ẹgbẹ YAF, ṣe sọ  rogbodiyan ọhun ni wọn sọ pe wọn yoo bẹrẹ lawọn ibi kan nilẹ Yoruba, nibi ti ẹmi eeyan ko ti ni jọ wọn loju ti yoo si dabi eyi to waye laye ijọba akọkọ lorileede yii ti wọn pe ni "Operation Wetie"

 

Bẹẹ ni wọn tun sọ pe awọn gbọ pe awọn mọdaru ọhun tun pinnu lati lo ẹgbẹ awọn akẹkọọ ati tawọn olukọ nileewe yunifasiti nilẹ Yoruba lati ba wọn fọwọsowọpọ lori wahala ti wọn fẹẹ bẹrẹ ọhun.

 

Animashun fi kun ọrọ ẹ pe gbogbo nnkan to fẹẹ da laaṣigbo ọhun silẹ ko ju imọtara ẹni nikan nidii oṣelu, ti wọn fẹẹ gba akoso bi idibo yoo ṣe waye, eyi ti wọn ro pe ijọba to wa lode yii ko fun wọn laaye.

 

Bakan naa ni wọn tun sọ pe erongba wọn ni pe ki wọn lo anfaani ijagbara orileede Yoruba lati fi tako ijọba apappọ, ki wọn si le pe wọn papọ, ki wọn jọ ṣadehun papọ, ti wọn yoo si fi raye gba akoso oṣelu.

 

Alakoso ẹgbẹ yii tun ṣalaye siwaju pe’ Ṣe ẹ ri gbogbo awọn ti wọn pinnu lati da wahala silẹ naa ni wọn ti ṣeleri lọkan wọn pe awọn yoo sọ orileede yii di ahoro lati ipinlẹ de ijọba apapọ’’

 

O waa rọ ẹgbẹ awọn akẹkọọ NANS ati ẹgbẹ awọn olukọ ASUU, lati ma ṣe jẹ ki wọn lo wọn lati da alaafia ilu ru, bẹẹ naa ni wọn tun rọ gbogbo awọn to n gbimọ lati da omi allafia ilu yii ru, ki wọn tete jawọ, nitori bi wọn    ba kọ ẹgbẹ YAF, ti ṣetan lati tu aṣiiri wọn sita.

 

Bakan naa ni wọn tun lo akoko naa lati gba awọn ọdọ Yoruba ati orileede Naijiria lapapọ nimọran lati ma ṣe jẹ ki wọn tan wọn jẹ, ki wọn lo wọn lati fa ijangbọn. Wọn tun wa sọ fun ijọba apapọ ati tipinlẹ lati jẹ eto aabo wa kaakiri ki ibo ba fẹẹ bẹrẹ ati to ba pari..

 


No comments:

Post a Comment

Pages