Adijat Adeleye Ọladapọ n gbaradi fun ile igbimo asoju-sofin l' Abuja - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 15 March 2022

Adijat Adeleye Ọladapọ n gbaradi fun ile igbimo asoju-sofin l' Abuja


Beeyan ba de aarin awọn ọlọselu Ifọ, Ewekoro, nipinlẹ Ogun, paapaa julọ awọn obinrin, orin kan ṣoṣo ti wọn jẹ lẹnu bayii ni pe obinrin lawọn fẹẹ ko lọ soju awọn nile-igbimọ aṣoju-ṣofin, niluu Abuja, ko tun waa ṣe pe obinrin naa bi ko ṣe Ọnarebu Adijat Motunrayọ  Adelẹyẹ Ọladapọ.

Wọn ko fọrọ naa ṣere o, bẹẹ lo si jẹ pe ki i ṣe aarin awọn obinrin nikan, awọn ọdọ paapaa sọ pe awọn ti ṣetan lati ṣatilẹyin fun ẹni to jẹ oludamọran gomina lori ọrọ awọn obinrin yii, niwọngba to ba loun fẹẹ jade dupo gẹgẹ bi aṣoju-ṣofin niluu Abuja, labẹ ẹgbẹ oṣelu APC.

Won ni ko digba to ba sọ oun fẹẹ jade kawọn to gbarukutu tii, nitori ọpọ awọn eeyan to ti ran lọwọ lakooko to fi wa nipo ọmọ ile igbimọ aṣofin, nipinlẹ Ogun, nibi to ti n ṣoju ẹkun Ifọ Keji.

Ohun tawọn kan tun fi sọ pe awọn gba ti arẹwa obinrin naa ko ju ọpọlọ pipe ti Ọlọrun ọba oke fi taa lọrẹ, to si tun ni ẹmi iwa irẹlẹ. Idi niyi ti wọn fi sọ pe bi ogo ti n jẹ ti Ọlọrun, akọni obinrin yii ni yoo wọle fun ipo ọhun, iyẹn to ba ṣetan lati fi erongba ẹ han lati dije.

Bo tilẹ jẹ pe titi di akoko yii, wọn ni obinrin naa ko ti fi erongba ẹ han sita nitori awọn iṣẹ ti Gomina gbe siwaju ẹ, amọ, ohun to daju ni pe ohun eeyan ni ohun Ọlọrun, awọn ara Ifọ, lọkunrin ati lobinrin ti mura silẹ, ariwo ti wọn si n pa labẹlẹ ni pe ile igbimọ aṣoju-ṣofin, fọdun 2023, Adija ni o. Ọjọ ti obinrin naa yoo fi erongba ẹ han sita ni wọn n reti bayii.

 


No comments:

Post a Comment

Pages