Wọn yoo ṣe ifilọlẹ SWAGA tipinlẹ Kogi lọjọ Abamẹta ọsẹ yii. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 15 March 2022

Wọn yoo ṣe ifilọlẹ SWAGA tipinlẹ Kogi lọjọ Abamẹta ọsẹ yii.


 

Gbogbo eto lo ti to bayii fun igbalejo ẹgbẹ to n ri si  erongba ilẹ Yoruba iyẹn SWAGA, nipinlẹ Kogi, fun itẹsiwaju iṣẹ wọn lori erongba lati jẹ ki Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, di aarẹ ilẹ wa fun ibo to n bọ lọdun 2023.

 

Gẹgẹ bi atẹjade ti Ọnarebu Bọsun Ọladele, to jẹ akọwe ẹgbẹ ọhun fi sita, lo ti ṣalaye pe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọtunla, tii ṣe ọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii, ni irinajo naa yoo bẹrẹ ti yoo si pari lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkandinlogun, osu yii.

 

Igala ni wọn yoo kọkọ de lọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii nigba ti wọn yoo ṣabẹwo de afin Igala, ni nnkan bi aago mejila ọsan, to ba di aago mẹrin irọlẹ ọjọ naa ni wọn yoo tun de ọdọ Maigari, niluu Lokoja.

 

Lọjọ Furaide, tii ṣe ọjọ keji, ni wọn yoo de ọdọ Atta tilẹ Ebira, ni Okene ni nnkan bi aago mẹsan-an aarọ, ti wọn ba kuro nibẹ, wọn yoo tun ṣabẹwo lọọ sọdọ Ọbaro Kabba, ni aago kan ọsan.

 

Ọjọ Abamẹta, waa ni pabambari nigba ti wọn yoo ṣefilọlẹ SWAGA tipinlẹ Kogi, gbọngan Kafas Multi Purpose, to wa lọna Okene,atijọ Lọkọja nipinlẹ Kogi, ni eto ọhun yoo ti waye.

 


No comments:

Post a Comment

Pages