Yáyì di Àrẹ̀mọ-ọba ilẹ̀ Yewa, ni wọ́n bá ní kò sọ́rọ̀ mọ́ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 15 May 2022

Yáyì di Àrẹ̀mọ-ọba ilẹ̀ Yewa, ni wọ́n bá ní kò sọ́rọ̀ mọ́


 

Orin to n jade lẹnu awọn eeyan ti wọn wa nibi ayẹyẹ ifinijoye Arẹmọ-Ọba ilẹ Yewa, Sẹnetọ Solomọn Ọlamilekan, tọpọ mọ si Yayi, lẹyin ti Olu ilaro, Ọba Kehinde Olugbenle jawe oye le oun ati iyawo ẹ lori tan ni, ‘’Ooo ti moye yii jẹ, iwo nna, iwo n papa, iwo n na’’

 

Ko le ṣe kọrọ maa ri bẹẹ, nitori lati ọdun to kọja, ti wọn ti kede pe wọn fẹẹ fi ọkunrin naa joye pe oun lo tọ si, oun lo si yẹ, lawọn awuyewuye kan ti n lọ nigboro ilẹ Yewa, nitori awọn kan ti inu wọn ko dun si.

 

Ṣugbọn Satide ọjọ Abamẹta, to kọja yii, ni Olu ilẹ Yewa, to tun jẹ Olu Ilaro, Ọba Kehinde Olugbenle, fi ontẹ lu u nipa jija ewe oye le ọkunrin naa lori, to si di Arẹmọ-ọba fun gbogbo ilẹ Yewa.

 

Ayẹyẹ ọhun lo waye ni papa Empire, niluu Ilaro, nibi tawọn eeyan jakanjakan lawujọ ti peju pesẹ, bẹẹ  ni wọn tun lo anfaani oye jijẹ yii lati fi sami ayẹyẹ ọdun kẹwaa ti Ọba Olugbenle dori oye.

 

Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun lo ṣaaju awọn eeyan ipinlẹ Ogun wa sibẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba ati Ọtunba Gbenga Daniel, tawọn naa ti jẹ Gomina tẹlẹ nipinlẹ ọhun naa, waa fi ijokoo yẹ oloye tuntun ọhun si.

 

Bẹẹ naa ni Igbakeji Gomina nipinlẹ Eko, Fẹmi Hamzat naa ṣaaju awọn tipinlẹ Eko naa wa, Awọn aṣofin lati Abuja, aṣoju-ṣofin, ọmọ ile igbimọ aṣofin ni Eko ati Ogun naa wa nibẹ pẹlu.

Bakan naa ni Olu ilaro, tun lo akoko naa, lati fawọn kan joye lọjọ naa, awọn naa ni iyawo Yayi, Temitọpẹ  to joye Yeye Arẹmọ-ọba, Ọtunba Akeem Ade Adigun(Sokopao)  joye  Apagunpọtẹ ilẹ Yewa, Alaaji Ibrahim Dende Egungbohun naa di Oluọmọ ati Salmot Badaru, igbakeji Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun naa jẹ Bẹẹrẹ ilẹ Yewa.

 

Lẹyin ti wọn ṣetan, ni wọn lọọ si gbọgan kan ninu ọgba poli Ilaro, nibi ti wọn ti ṣefilọlẹ iwe itan ọba naa pẹlu,ti Alhaji Aliko Dangote, Ahmed Lawan, to jẹ aarẹ nile igbimọ aṣofin niluu Abuja ati Oloye Kessington Adebutu,ran awọn aṣoju wa lati bawọn ṣefilọlẹ iwe ọhun.

 

Agba olorin fuji nni, Wasiu Ayinde, lo fere da wọn lara ya ninu gbọngan naa.

 


No comments:

Post a Comment

Pages