Lati le jẹ ki erogba wọn jọ lori ki tikẹẹti ipo aarẹ ja mọ Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lọwọ, ko si le depo ọhun, ẹgbẹ to n ri erongba ilẹ Yoruba fun ti Asiwaju iyẹn South West Agenda for Asiwaju 2023, (SWAGA '23) , yoo ṣefilọlẹ ẹgbẹ naa ti wọn pe ni ‘’NORTH CENTRAL AGENDA for ASIWAJU 2023´´ (NCA ti ipinlẹ Kwara.
Gẹgẹ bi atẹjade ti akọwe ẹgbẹ naa lapapọ, Ọnarebu Bọsun Ọladele, fi sita, lo ti ṣalaye pe irinajo ọhun to yoo gba wọn lọjọ mẹta, lawọn ti bẹrẹ ẹ ni oni yii. O sọ pe aarọ ati ọsan lawọn fi ni eto ti wọn yoo ṣe ti gbogbo ẹ si da lori ilakaka wọn lori Aṣiwaju Bọla Ahmed.
O ṣalaye pe ẹgbẹ SWAGA, ni wọn ti rin iriajo kaakiri ilẹ Yoruba fun ipolongo erongba wọn lori ipo aarẹ ọhun ko tiẹ to di pe Bọla Ahmed gan-an jade lati dupo.
Gẹgẹ bi awọn eto ti wọn ti la silẹ fun irinajo ọhun, ni bi gbogbo awọn ẹgbẹ naa ti ṣe wa ni Ilọrin fun imurasilẹ bayii. Ọla ọjọ Aje, Monde, ni wọn yoo ṣabẹwo lọọ sọdọ awọn ọba alade kaakiri ipinlẹ naa.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, tii ṣe ọjọ ketadinlogun, osu, ni wọn yoo ṣefilọlẹ ẹgbẹ naa. Awọn ti wọn yoo ṣaaju ikọ SAWGA’23 lapapọ ni alaga wọn Sẹnetọ Dayọ Adeyẹye, Sẹnetọ Adesọji Akanbi, igbakeji alaga,Ọnarebu Oyetunde Ojo, Ọnarebu Ayọ Omidiran, Ọnarebu Ifẹdayọ Abegunde, Alagba Ọlọruntọba Ọkẹ atawọn yooku.
No comments:
Post a Comment